Quran Apps in many lanuages:

Surah At-Talaq Ayahs #6 Translated in Yoruba

فَإِذَا بَلَغْنَ أَجَلَهُنَّ فَأَمْسِكُوهُنَّ بِمَعْرُوفٍ أَوْ فَارِقُوهُنَّ بِمَعْرُوفٍ وَأَشْهِدُوا ذَوَيْ عَدْلٍ مِنْكُمْ وَأَقِيمُوا الشَّهَادَةَ لِلَّهِ ۚ ذَٰلِكُمْ يُوعَظُ بِهِ مَنْ كَانَ يُؤْمِنُ بِاللَّهِ وَالْيَوْمِ الْآخِرِ ۚ وَمَنْ يَتَّقِ اللَّهَ يَجْعَلْ لَهُ مَخْرَجًا
Nigba ti won ba fe pari onka ojo opo won, e mu won modo ni ona t’o dara tabi ki e ko won sile ni ona t’o dara. E fi awon onideede meji ninu yin jerii si i. Ki e si gbe ijerii naa duro ni titori ti Allahu. Iyen ni A n fi se waasi fun enikeni ti o ba ni igbagbo ododo ninu Allahu ati Ojo Ikeyin. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa fun un ni ona abayo (ninu isoro)
وَيَرْزُقْهُ مِنْ حَيْثُ لَا يَحْتَسِبُ ۚ وَمَنْ يَتَوَكَّلْ عَلَى اللَّهِ فَهُوَ حَسْبُهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ بَالِغُ أَمْرِهِ ۚ قَدْ جَعَلَ اللَّهُ لِكُلِّ شَيْءٍ قَدْرًا
O si maa pese fun un ni aye ti ko ti rokan. Ati pe enikeni ti o ba gbekele Allahu, O maa to o. Dajudaju Allahu yoo mu oro Re de opin. Dajudaju Allahu ti ko odiwon akoko fun gbogbo nnkan
وَاللَّائِي يَئِسْنَ مِنَ الْمَحِيضِ مِنْ نِسَائِكُمْ إِنِ ارْتَبْتُمْ فَعِدَّتُهُنَّ ثَلَاثَةُ أَشْهُرٍ وَاللَّائِي لَمْ يَحِضْنَ ۚ وَأُولَاتُ الْأَحْمَالِ أَجَلُهُنَّ أَنْ يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ ۚ وَمَنْ يَتَّقِ اللَّهَ يَجْعَلْ لَهُ مِنْ أَمْرِهِ يُسْرًا
Awon obinrin t’o ti soreti nu nipa nnkan osu sise ninu awon obinrin yin, ti e ba seyemeji, onka ojo ikosile won ni osu meta. (Bee naa ni fun) awon ti ko ti i maa se nnkan osu. Awon oloyun, ipari onka ojo opo ikosile tiwon ni pe ki won bi oyun inu won. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa se oro re ni irorun
ذَٰلِكَ أَمْرُ اللَّهِ أَنْزَلَهُ إِلَيْكُمْ ۚ وَمَنْ يَتَّقِ اللَّهَ يُكَفِّرْ عَنْهُ سَيِّئَاتِهِ وَيُعْظِمْ لَهُ أَجْرًا
Iyen ni ase Allahu, ti O sokale fun yin. Enikeni ti o ba n beru Allahu, O maa pa awon asise re re. O si maa je ki esan re tobi
أَسْكِنُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ سَكَنْتُمْ مِنْ وُجْدِكُمْ وَلَا تُضَارُّوهُنَّ لِتُضَيِّقُوا عَلَيْهِنَّ ۚ وَإِنْ كُنَّ أُولَاتِ حَمْلٍ فَأَنْفِقُوا عَلَيْهِنَّ حَتَّىٰ يَضَعْنَ حَمْلَهُنَّ ۚ فَإِنْ أَرْضَعْنَ لَكُمْ فَآتُوهُنَّ أُجُورَهُنَّ ۖ وَأْتَمِرُوا بَيْنَكُمْ بِمَعْرُوفٍ ۖ وَإِنْ تَعَاسَرْتُمْ فَسَتُرْضِعُ لَهُ أُخْرَىٰ
E fun won ni ibugbe ninu ibugbe yin bi aye se gba yin mo. E ma se ni won lara lati ko ifunpinpin ba won. Ti won ba je oloyun, e nawo le won lori titi won yoo fi bi oyun inu won. Ti won ba n fun omo yin ni oyan mu, e fun won ni owo-oya won. E damoran laaarin ara yin ni ona t’o dara. Ti oro ko ba si rogbo laaarin ara yin, ki elomiiran ba oko (fun omo) ni oyan mu

Choose other languages: