Quran Apps in many lanuages:

Surah Ash-Shura Ayahs #24 Translated in Yoruba

مَنْ كَانَ يُرِيدُ حَرْثَ الْآخِرَةِ نَزِدْ لَهُ فِي حَرْثِهِ ۖ وَمَنْ كَانَ يُرِيدُ حَرْثَ الدُّنْيَا نُؤْتِهِ مِنْهَا وَمَا لَهُ فِي الْآخِرَةِ مِنْ نَصِيبٍ
Enikeni ti o ba gbero lati gba eso (ise re ni) orun, A maa se alekun si eso re fun un. Enikeni ti o ba si gbero lati gba eso (ise re ni) aye, A maa fun un ninu re. Ko si nii si ipin kan kan fun un mo ni orun
أَمْ لَهُمْ شُرَكَاءُ شَرَعُوا لَهُمْ مِنَ الدِّينِ مَا لَمْ يَأْذَنْ بِهِ اللَّهُ ۚ وَلَوْلَا كَلِمَةُ الْفَصْلِ لَقُضِيَ بَيْنَهُمْ ۗ وَإِنَّ الظَّالِمِينَ لَهُمْ عَذَابٌ أَلِيمٌ
Tabi won ni awon orisa kan t’o sofin (iborisa) fun won ninu esin, eyi ti Allahu ko yonda re? Ti ko ba je ti oro asoyan (pe A o nii kanju je won niya), Awa iba ti mu idajo wa laaarin won. Dajudaju awon alabosi, iya eleta-elero si wa fun won
تَرَى الظَّالِمِينَ مُشْفِقِينَ مِمَّا كَسَبُوا وَهُوَ وَاقِعٌ بِهِمْ ۗ وَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فِي رَوْضَاتِ الْجَنَّاتِ ۖ لَهُمْ مَا يَشَاءُونَ عِنْدَ رَبِّهِمْ ۚ ذَٰلِكَ هُوَ الْفَضْلُ الْكَبِيرُ
O maa ri awon alabosi ti won yoo maa paya nitori ohun ti won se nise, ti o si maa ko le won lori. Awon t’o si gbagbo ni ododo, ti won se ise rere maa wa ni awon aye t’o rewa julo ninu Ogba Idera. Ohun ti won ba n fe maa wa fun won ni odo Oluwa won. Iyen, ohun ni oore ajulo t’o tobi
ذَٰلِكَ الَّذِي يُبَشِّرُ اللَّهُ عِبَادَهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ۗ قُلْ لَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ أَجْرًا إِلَّا الْمَوَدَّةَ فِي الْقُرْبَىٰ ۗ وَمَنْ يَقْتَرِفْ حَسَنَةً نَزِدْ لَهُ فِيهَا حُسْنًا ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ شَكُورٌ
Iyen ni eyi ti Allahu fi n se iro idunnu fun awon erusin Re, awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere. So pe: "Emi ko beere owo-oya lowo yin lori re bi ko se ife ebi.” Enikeni ti o ba se rere kan, A maa se alekun rere fun un. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Olope
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا ۖ فَإِنْ يَشَإِ اللَّهُ يَخْتِمْ عَلَىٰ قَلْبِكَ ۗ وَيَمْحُ اللَّهُ الْبَاطِلَ وَيُحِقُّ الْحَقَّ بِكَلِمَاتِهِ ۚ إِنَّهُ عَلِيمٌ بِذَاتِ الصُّدُورِ
Tabi won n wi pe: "O da adapa iro mo Allahu ni?" Nitori naa, ti Allahu ba fe, O maa fi edidi di okan re pa. Ati pe Allahu yoo pa iro re. O si maa fi ododo rinle pelu oro Re. Dajudaju Oun ni Onimo nipa ohun t’o wa ninu igba-aya eda

Choose other languages: