Surah Ar-Rum Ayahs #57 Translated in Yoruba
وَمَا أَنْتَ بِهَادِ الْعُمْيِ عَنْ ضَلَالَتِهِمْ ۖ إِنْ تُسْمِعُ إِلَّا مَنْ يُؤْمِنُ بِآيَاتِنَا فَهُمْ مُسْلِمُونَ
Iwo ko l’o maa fi ona mo awon afoju nibi isina won. Ko si eni ti o maa mu gbo oro afi eni ti o ba gba awon ayah Wa gbo. Awon si ni (musulumi) olujupa-juse-sile fun Allahu. Allahu (subhanahu wa ta’ala) l’O n sise iyanu. Ko si si Anabi tabi Ojise Olohun kan ti Allahu ko fun ni ise iyanu kan tabi omiran se ni ibamu si igba eni kookan won. Bee si ni eyikeyii ise iyanu ti o ba towo Anabi tabi Ojise kan waye ko so Anabi tabi Ojise naa di oluwa ati olugbala. Allahu nikan soso ni Oluwa ati Olugbala aye ati orun. Nitori naa fun alekun lori awon ise iyanu Anabi ‘Isa omo Moryam (’alaehi-ssolatu wa-ssalam) ti Allahu ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan. Amo awon kristieni gege bi isesi won bi o se n wu u to ati bi o se n jerankan to ni pe ki gbogbo awon eniyan re gbagbo ninu Allahu. Amo won ko gbagbo
اللَّهُ الَّذِي خَلَقَكُمْ مِنْ ضَعْفٍ ثُمَّ جَعَلَ مِنْ بَعْدِ ضَعْفٍ قُوَّةً ثُمَّ جَعَلَ مِنْ بَعْدِ قُوَّةٍ ضَعْفًا وَشَيْبَةً ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۖ وَهُوَ الْعَلِيمُ الْقَدِيرُ
Allahu, Eni ti O seda yin lati (ara nnkan) lile, leyin naa, leyin lile O fun (yin ni) agbara, leyin naa, leyin agbara, O tun fi lile ati ogbo (si yin lara). O n da ohunkohun ti O ba fe. Oun si ni Onimo, Alagbara
وَيَوْمَ تَقُومُ السَّاعَةُ يُقْسِمُ الْمُجْرِمُونَ مَا لَبِثُوا غَيْرَ سَاعَةٍ ۚ كَذَٰلِكَ كَانُوا يُؤْفَكُونَ
Ati pe ni ojo ti Akoko naa ba sele (iyen, ojo Ajinde), awon elese yoo maa bura pe awon ko gbe (ile aye) ju akoko kan lo.” Bayen ni won se maa n f’iro tanra won je
وَقَالَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ وَالْإِيمَانَ لَقَدْ لَبِثْتُمْ فِي كِتَابِ اللَّهِ إِلَىٰ يَوْمِ الْبَعْثِ ۖ فَهَٰذَا يَوْمُ الْبَعْثِ وَلَٰكِنَّكُمْ كُنْتُمْ لَا تَعْلَمُونَ
Awon ti A fun ni imo ati igbagbo ododo yoo so pe: “Dajudaju ninu akosile ti Allahu, e ti gbe ile aye titi Ojo Ajinde (fi to). Nitori naa, eyi ni Ojo Ajinde, sugbon eyin ko mo.”
فَيَوْمَئِذٍ لَا يَنْفَعُ الَّذِينَ ظَلَمُوا مَعْذِرَتُهُمْ وَلَا هُمْ يُسْتَعْتَبُونَ
Nitori naa ni ojo yen, awon t’o sabosi, awawi won ko nii se won ni anfaani. Won ko si nii fun won ni aye lati se ohun ti won yoo fi ri iyonu Allahu
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
