Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rum Ayahs #52 Translated in Yoruba

اللَّهُ الَّذِي يُرْسِلُ الرِّيَاحَ فَتُثِيرُ سَحَابًا فَيَبْسُطُهُ فِي السَّمَاءِ كَيْفَ يَشَاءُ وَيَجْعَلُهُ كِسَفًا فَتَرَى الْوَدْقَ يَخْرُجُ مِنْ خِلَالِهِ ۖ فَإِذَا أَصَابَ بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ إِذَا هُمْ يَسْتَبْشِرُونَ
Allahu ni Eni t’O n fi awon ategun ranse. (Ategun naa) si maa tu esujo soke. (Allahu) yo si te (esujo) sile s’oju sanmo bi O ba se fe. O si maa da a kelekele (si oju sanmo). O si maa ri ojo ti o ma maa jade laaarin re. Nigba ti O ba si ro (ojo naa) fun eni ti O ba fe ninu awon erusin Re, nigba naa won yo si maa dunnu
وَإِنْ كَانُوا مِنْ قَبْلِ أَنْ يُنَزَّلَ عَلَيْهِمْ مِنْ قَبْلِهِ لَمُبْلِسِينَ
Bi o tile je pe siwaju ki O to so o kale fun won, won ti soreti nu siwaju re
فَانْظُرْ إِلَىٰ آثَارِ رَحْمَتِ اللَّهِ كَيْفَ يُحْيِي الْأَرْضَ بَعْدَ مَوْتِهَا ۚ إِنَّ ذَٰلِكَ لَمُحْيِي الْمَوْتَىٰ ۖ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Nitori naa, woye si awon oripa ike Allahu, (wo) bi (Allahu) se n ta ile ji leyin ti ile ti ku. Dajudaju (Allahu) yii ni O kuku maa so awon oku di alaaye. Oun si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
وَلَئِنْ أَرْسَلْنَا رِيحًا فَرَأَوْهُ مُصْفَرًّا لَظَلُّوا مِنْ بَعْدِهِ يَكْفُرُونَ
Dajudaju ti A ba ran ategun kan (si won), ki won si ri (nnkan ogbin won) ni pipon (jijona), dajudaju won yo si maa sai moore lo leyin re
فَإِنَّكَ لَا تُسْمِعُ الْمَوْتَىٰ وَلَا تُسْمِعُ الصُّمَّ الدُّعَاءَ إِذَا وَلَّوْا مُدْبِرِينَ
Dajudaju iwo ko l’o maa mu awon oku gboro. O o si nii mu awon aditi gbo ipe nigba ti won ba keyin si o, ti won n lo

Choose other languages: