Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rad Ayahs #8 Translated in Yoruba

وَفِي الْأَرْضِ قِطَعٌ مُتَجَاوِرَاتٌ وَجَنَّاتٌ مِنْ أَعْنَابٍ وَزَرْعٌ وَنَخِيلٌ صِنْوَانٌ وَغَيْرُ صِنْوَانٍ يُسْقَىٰ بِمَاءٍ وَاحِدٍ وَنُفَضِّلُ بَعْضَهَا عَلَىٰ بَعْضٍ فِي الْأُكُلِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يَعْقِلُونَ
O tun wa ninu ile awon abala-abala ile (oniran-anran) t’o wa nitosi ara won ati awon ogba oko ajara, irugbin ati igi dabinu t’o peka ati eyi ti ko peka, ti won n fi omi eyo kan won. (Sibesibe) A se ajulo fun apa kan re lori apa kan nibi jije. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo t’o ni laakaye
وَإِنْ تَعْجَبْ فَعَجَبٌ قَوْلُهُمْ أَإِذَا كُنَّا تُرَابًا أَإِنَّا لَفِي خَلْقٍ جَدِيدٍ ۗ أُولَٰئِكَ الَّذِينَ كَفَرُوا بِرَبِّهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ الْأَغْلَالُ فِي أَعْنَاقِهِمْ ۖ وَأُولَٰئِكَ أَصْحَابُ النَّارِ ۖ هُمْ فِيهَا خَالِدُونَ
Ti o ba seemo, eemo ma ni oro (enu) won (nipa bi won se so pe): “Se nigba ti a ba ti di erupe tan, se nigba naa ni awa yoo tun di eda titun?” Awon wonyen ni awon t’o sai gbagbo ninu Oluwa won. Awon wonyen ni ewon n be lorun won. Awon wonyen si ni ero inu Ina. Olusegbere ni won ninu re
وَيَسْتَعْجِلُونَكَ بِالسَّيِّئَةِ قَبْلَ الْحَسَنَةِ وَقَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِهِمُ الْمَثُلَاتُ ۗ وَإِنَّ رَبَّكَ لَذُو مَغْفِرَةٍ لِلنَّاسِ عَلَىٰ ظُلْمِهِمْ ۖ وَإِنَّ رَبَّكَ لَشَدِيدُ الْعِقَابِ
Won tun n kan o loju pe ki aburu sele siwaju rere. Awon apeere iya kuku ti sele siwaju won. Ati pe dajudaju Oluwa re ni Alaforijin fun awon eniyan lori abosi (owo) won. Dajudaju Oluwa re le nibi iya
وَيَقُولُ الَّذِينَ كَفَرُوا لَوْلَا أُنْزِلَ عَلَيْهِ آيَةٌ مِنْ رَبِّهِ ۗ إِنَّمَا أَنْتَ مُنْذِرٌ ۖ وَلِكُلِّ قَوْمٍ هَادٍ
Awon t’o sai gbagbo n wi pe: “Ki ni ko je ki Won so ami kan kale fun un lati odo Oluwa re?” Olukilo ma ni iwo. Olutosona si wa fun ijo kookan
اللَّهُ يَعْلَمُ مَا تَحْمِلُ كُلُّ أُنْثَىٰ وَمَا تَغِيضُ الْأَرْحَامُ وَمَا تَزْدَادُ ۖ وَكُلُّ شَيْءٍ عِنْدَهُ بِمِقْدَارٍ
Allahu mo ohun ti obinrin kookan ni loyun ati ohun ti ile omo yoo fi din ku (ninu ojo ibimo) ati ohun ti o maa fi lekun. Nnkan kookan l’o si ni odiwon lodo Re

Choose other languages: