Quran Apps in many lanuages:

Surah Ar-Rad Ayahs #25 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ يَصِلُونَ مَا أَمَرَ اللَّهُ بِهِ أَنْ يُوصَلَ وَيَخْشَوْنَ رَبَّهُمْ وَيَخَافُونَ سُوءَ الْحِسَابِ
(Awon ni) awon t’o n da ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo po. Won n paya Oluwa won. Won si n paya aburu isiro-ise
وَالَّذِينَ صَبَرُوا ابْتِغَاءَ وَجْهِ رَبِّهِمْ وَأَقَامُوا الصَّلَاةَ وَأَنْفَقُوا مِمَّا رَزَقْنَاهُمْ سِرًّا وَعَلَانِيَةً وَيَدْرَءُونَ بِالْحَسَنَةِ السَّيِّئَةَ أُولَٰئِكَ لَهُمْ عُقْبَى الدَّارِ
(Awon ni) awon t’o se suuru lati fi wa Oju rere Oluwa won. Won n kirun. Won n na ninu ohun ti A pese fun won ni ikoko ati ni gbangba. Won si n fi rere ti aburu lo. Awon wonyen ni atubotan Ile rere n be fun
جَنَّاتُ عَدْنٍ يَدْخُلُونَهَا وَمَنْ صَلَحَ مِنْ آبَائِهِمْ وَأَزْوَاجِهِمْ وَذُرِّيَّاتِهِمْ ۖ وَالْمَلَائِكَةُ يَدْخُلُونَ عَلَيْهِمْ مِنْ كُلِّ بَابٍ
Inu awon Ogba Idera gbere ni won yoo wo, (awon) ati eni t’o ba se rere ninu awon baba won, awon iyawo won ati awon aromodomo won. Awon molaika yo si maa wole to won lati enu ona kookan
سَلَامٌ عَلَيْكُمْ بِمَا صَبَرْتُمْ ۚ فَنِعْمَ عُقْبَى الدَّارِ
(Won yoo so pe): “Alaafia fun yin nitori ifarada yin.” Atubotan Ile naa si dara
وَالَّذِينَ يَنْقُضُونَ عَهْدَ اللَّهِ مِنْ بَعْدِ مِيثَاقِهِ وَيَقْطَعُونَ مَا أَمَرَ اللَّهُ بِهِ أَنْ يُوصَلَ وَيُفْسِدُونَ فِي الْأَرْضِ ۙ أُولَٰئِكَ لَهُمُ اللَّعْنَةُ وَلَهُمْ سُوءُ الدَّارِ
Awon t’o n tu adehun Allahu leyin ti won ti gba adehun Re, ti won n ja ohun ti Allahu pa lase pe ki won dapo, ti won si n se ibaje lori ile; awon wonyen ni egun wa fun. Ati pe Ile (Ina) buruku wa fun won

Choose other languages: