Surah An-Nur Ayahs #36 Translated in Yoruba
وَأَنْكِحُوا الْأَيَامَىٰ مِنْكُمْ وَالصَّالِحِينَ مِنْ عِبَادِكُمْ وَإِمَائِكُمْ ۚ إِنْ يَكُونُوا فُقَرَاءَ يُغْنِهِمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ ۗ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ
E fi iyawo fun awon apon ninu yin ati awon eni ire ninu awon erukunrin yin. (Ki e si wa oko rere fun) awon erubinrin yin. Ti won ba je alaini, Allahu yoo ro won loro ninu ola Re. Allahu si ni Olugbaaye, Onimo
وَلْيَسْتَعْفِفِ الَّذِينَ لَا يَجِدُونَ نِكَاحًا حَتَّىٰ يُغْنِيَهُمُ اللَّهُ مِنْ فَضْلِهِ ۗ وَالَّذِينَ يَبْتَغُونَ الْكِتَابَ مِمَّا مَلَكَتْ أَيْمَانُكُمْ فَكَاتِبُوهُمْ إِنْ عَلِمْتُمْ فِيهِمْ خَيْرًا ۖ وَآتُوهُمْ مِنْ مَالِ اللَّهِ الَّذِي آتَاكُمْ ۚ وَلَا تُكْرِهُوا فَتَيَاتِكُمْ عَلَى الْبِغَاءِ إِنْ أَرَدْنَ تَحَصُّنًا لِتَبْتَغُوا عَرَضَ الْحَيَاةِ الدُّنْيَا ۚ وَمَنْ يُكْرِهْهُنَّ فَإِنَّ اللَّهَ مِنْ بَعْدِ إِكْرَاهِهِنَّ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Ki awon ti ko ri (owo lati fe) iyawo mu oju won kuro nibi isekuse titi Allahu yoo fi ro won loro ninu ola Re.1 Awon t’o n wa iwe ominira ninu awon eru yin, e ko iwe ominira fun won ti e ba mo ohun rere nipa won. Ki e si fun won ninu dukia Allahu ti O fun yin. (Nitori dukia aye ti e n wa), e ma se je awon erubinrin yin nipa lati lo se sina, ti won ba fe so abe won nibi isekuse.2 Enikeni ti o ba je won nipa, dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun leyin ti e ti je won nipa
وَلَقَدْ أَنْزَلْنَا إِلَيْكُمْ آيَاتٍ مُبَيِّنَاتٍ وَمَثَلًا مِنَ الَّذِينَ خَلَوْا مِنْ قَبْلِكُمْ وَمَوْعِظَةً لِلْمُتَّقِينَ
Dajudaju A ti so awon ami t’o yanju, itan awon t’o ti lo siwaju yin ati waasi fun awon oluberu (Allahu) kale fun yin
اللَّهُ نُورُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۚ مَثَلُ نُورِهِ كَمِشْكَاةٍ فِيهَا مِصْبَاحٌ ۖ الْمِصْبَاحُ فِي زُجَاجَةٍ ۖ الزُّجَاجَةُ كَأَنَّهَا كَوْكَبٌ دُرِّيٌّ يُوقَدُ مِنْ شَجَرَةٍ مُبَارَكَةٍ زَيْتُونَةٍ لَا شَرْقِيَّةٍ وَلَا غَرْبِيَّةٍ يَكَادُ زَيْتُهَا يُضِيءُ وَلَوْ لَمْ تَمْسَسْهُ نَارٌ ۚ نُورٌ عَلَىٰ نُورٍ ۗ يَهْدِي اللَّهُ لِنُورِهِ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَيَضْرِبُ اللَّهُ الْأَمْثَالَ لِلنَّاسِ ۗ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Allahu ni Olutan-imole sinu awon sanmo ati ile. Apejuwe imole Re da bi opo atupa kan ti atupa wa ninu re. Atupa naa si wa ninu dingi. Dingi naa da bi irawo kan t’o n tan yanranyanran. Won n tan (imole naa) lati ara igi ibukun kan, igi zaetun. Ki i gba imole nigba ti oorun ba n yo jade tabi nigba ti oorun ba n wo. Epo (imole) re fee da mu imole wa, ina ibaa ma de ibe. Imole lori imole ni. Allahu n to enikeni ti O ba fe si (ona) imole Re. Allahu n fi awon akawe lele fun awon eniyan. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan
فِي بُيُوتٍ أَذِنَ اللَّهُ أَنْ تُرْفَعَ وَيُذْكَرَ فِيهَا اسْمُهُ يُسَبِّحُ لَهُ فِيهَا بِالْغُدُوِّ وَالْآصَالِ
(Awon atupa ibukun naa wa) ninu awon ile kan (iyen awon mosalasi) eyi ti Allahu yonda pe ki won gbega,1 ki won si maa daruko Re ninu re. (Awon eniyan) yo si maa safomo fun Un ninu re ni aaro ati asale
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
