Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #99 Translated in Yoruba

لَا يَسْتَوِي الْقَاعِدُونَ مِنَ الْمُؤْمِنِينَ غَيْرُ أُولِي الضَّرَرِ وَالْمُجَاهِدُونَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ ۚ فَضَّلَ اللَّهُ الْمُجَاهِدِينَ بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ عَلَى الْقَاعِدِينَ دَرَجَةً ۚ وَكُلًّا وَعَدَ اللَّهُ الْحُسْنَىٰ ۚ وَفَضَّلَ اللَّهُ الْمُجَاهِدِينَ عَلَى الْقَاعِدِينَ أَجْرًا عَظِيمًا
Awon olujokoo sinu ile ninu awon onigbagbo ododo, yato si awon alailera, ati awon olujagun fun esin Allahu pelu dukia won ati emi won, won ko dogba. Allahu fi ipo kan soore ajulo fun awon olujagun fun esin Allahu pelu dukia won ati emi won lori awon olujokoo sinu ile. Olukuluku (won) ni Allahu se adehun ohun rere (Ogba Idera) fun. Allahu gbola fun awon olujagun esin lori awon olujokoo sinu ile pelu esan nla
دَرَجَاتٍ مِنْهُ وَمَغْفِرَةً وَرَحْمَةً ۚ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
awon ipo kan, aforijin ati aanu lati odo Re. Allahu si n je Alaforijin Asake-orun
إِنَّ الَّذِينَ تَوَفَّاهُمُ الْمَلَائِكَةُ ظَالِمِي أَنْفُسِهِمْ قَالُوا فِيمَ كُنْتُمْ ۖ قَالُوا كُنَّا مُسْتَضْعَفِينَ فِي الْأَرْضِ ۚ قَالُوا أَلَمْ تَكُنْ أَرْضُ اللَّهِ وَاسِعَةً فَتُهَاجِرُوا فِيهَا ۚ فَأُولَٰئِكَ مَأْوَاهُمْ جَهَنَّمُ ۖ وَسَاءَتْ مَصِيرًا
Dajudaju awon ti molaika gba emi won, (lasiko) ti won n sabosi si emi ara won, (awon molaika) so pe: “Ki ni e n se (ninu esin)?” Won wi pe: “Won da wa lagara lori ile ni.” (Awon molaika) so pe: “Se ile Allahu ko fe to (fun yin) lati gbe esin yin sa lori ile?” Awon wonyen, ina Jahanamo ni ibugbe won. O si buru ni ikangun
إِلَّا الْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الرِّجَالِ وَالنِّسَاءِ وَالْوِلْدَانِ لَا يَسْتَطِيعُونَ حِيلَةً وَلَا يَهْتَدُونَ سَبِيلًا
Ayafi awon alailagbara ninu awon okunrin, awon obinrin ati awon omode ti ko ni ikapa ogbon kan, ti won ko si da ona mo (de ilu Modinah)
فَأُولَٰئِكَ عَسَى اللَّهُ أَنْ يَعْفُوَ عَنْهُمْ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَفُوًّا غَفُورًا
Nitori naa, awon wonyen, o sunmo ki Allahu samojukuro fun won. Allahu si n je Alamojuukuro, Alaforijin

Choose other languages: