Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #9 Translated in Yoruba

4:5
وَلَا تُؤْتُوا السُّفَهَاءَ أَمْوَالَكُمُ الَّتِي جَعَلَ اللَّهُ لَكُمْ قِيَامًا وَارْزُقُوهُمْ فِيهَا وَاكْسُوهُمْ وَقُولُوا لَهُمْ قَوْلًا مَعْرُوفًا
E ma se ko dukia yin ti Allahu fi se gbemiiro fun yin le awon alailoye lowo. E pese ije-imu fun won ninu re, ki e si raso fun won. Ki e si maa soro daadaa fun won
4:6
وَابْتَلُوا الْيَتَامَىٰ حَتَّىٰ إِذَا بَلَغُوا النِّكَاحَ فَإِنْ آنَسْتُمْ مِنْهُمْ رُشْدًا فَادْفَعُوا إِلَيْهِمْ أَمْوَالَهُمْ ۖ وَلَا تَأْكُلُوهَا إِسْرَافًا وَبِدَارًا أَنْ يَكْبَرُوا ۚ وَمَنْ كَانَ غَنِيًّا فَلْيَسْتَعْفِفْ ۖ وَمَنْ كَانَ فَقِيرًا فَلْيَأْكُلْ بِالْمَعْرُوفِ ۚ فَإِذَا دَفَعْتُمْ إِلَيْهِمْ أَمْوَالَهُمْ فَأَشْهِدُوا عَلَيْهِمْ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ حَسِيبًا
E maa sagbeyewo (oye) awon omo orukan titi won yoo fi to igbeyawo se. Ti e ba si ti ri oye lara won, ki e da dukia won pada fun won. E o gbodo je dukia won ni ije apa ati ijekuje ki won to dagba. Eni ti o ba je oloro, ki o moju kuro (nibe). Eni ti o ba je alaini, ki o je ninu re ni ona t’o dara. Nitori naa, ti e ba fe da dukia won pada fun won, e pe awon elerii si won. Allahu si to ni Olusiro
4:7
لِلرِّجَالِ نَصِيبٌ مِمَّا تَرَكَ الْوَالِدَانِ وَالْأَقْرَبُونَ وَلِلنِّسَاءِ نَصِيبٌ مِمَّا تَرَكَ الْوَالِدَانِ وَالْأَقْرَبُونَ مِمَّا قَلَّ مِنْهُ أَوْ كَثُرَ ۚ نَصِيبًا مَفْرُوضًا
Awon okunrin ni ipin ninu ohun ti obi mejeeji ati ebi fi sile. Ati pe awon obinrin naa ni ipin ninu ohun ti obi mejeeji ati ebi fi sile. Ninu ohun t’o kere ninu re tabi t’o po; (o je) ipin ti won ti pin (fun won)
4:8
وَإِذَا حَضَرَ الْقِسْمَةَ أُولُو الْقُرْبَىٰ وَالْيَتَامَىٰ وَالْمَسَاكِينُ فَارْزُقُوهُمْ مِنْهُ وَقُولُوا لَهُمْ قَوْلًا مَعْرُوفًا
Nigba ti awon ebi, awon omo orukan ati awon mekunnu ba wa ni (ijokoo) ogun pipin, e fun won ninu re (siwaju ki e to pin ogun), ki e si soro daadaa fun won
4:9
وَلْيَخْشَ الَّذِينَ لَوْ تَرَكُوا مِنْ خَلْفِهِمْ ذُرِّيَّةً ضِعَافًا خَافُوا عَلَيْهِمْ فَلْيَتَّقُوا اللَّهَ وَلْيَقُولُوا قَوْلًا سَدِيدًا
Awon (olupingun ati alagbawo omo orukan) ti o ba je pe awon naa maa fi omo wewe sile, ti won si n paya lori won, ki won yaa beru Allahu. Ki won si maa soro daadaa (fun omo orukan)

Choose other languages: