Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #46 Translated in Yoruba

يَوْمَئِذٍ يَوَدُّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَعَصَوُا الرَّسُولَ لَوْ تُسَوَّىٰ بِهِمُ الْأَرْضُ وَلَا يَكْتُمُونَ اللَّهَ حَدِيثًا
Ni ojo yen, awon t’o sai gbagbo, ti won si yapa Ojise, won a fe ki awon ba ile dogba (ki won di erupe). Won ko si le fi oro kan pamo fun Allahu
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَقْرَبُوا الصَّلَاةَ وَأَنْتُمْ سُكَارَىٰ حَتَّىٰ تَعْلَمُوا مَا تَقُولُونَ وَلَا جُنُبًا إِلَّا عَابِرِي سَبِيلٍ حَتَّىٰ تَغْتَسِلُوا ۚ وَإِنْ كُنْتُمْ مَرْضَىٰ أَوْ عَلَىٰ سَفَرٍ أَوْ جَاءَ أَحَدٌ مِنْكُمْ مِنَ الْغَائِطِ أَوْ لَامَسْتُمُ النِّسَاءَ فَلَمْ تَجِدُوا مَاءً فَتَيَمَّمُوا صَعِيدًا طَيِّبًا فَامْسَحُوا بِوُجُوهِكُمْ وَأَيْدِيكُمْ ۗ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَفُوًّا غَفُورًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se sunmo irun kiki nigba ti oti ba n pa yin titi e maa fi mo ohun ti e n so ati awon onijannaba, afi awon olukoja ninu mosalasi, titi e maa fi we (iwe jannaba). Ti e ba si je alaisan tabi e wa lori irin-ajo tabi okan ninu yin de lati ibi igbonse tabi e sunmo obinrin (yin), ti e ko ri omi, e fi erupe t’o dara se tayamomu; e fi pa oju yin ati owo yin. Dajudaju Allahu n je Alamoojukuro, Alaforijin
أَلَمْ تَرَ إِلَى الَّذِينَ أُوتُوا نَصِيبًا مِنَ الْكِتَابِ يَشْتَرُونَ الضَّلَالَةَ وَيُرِيدُونَ أَنْ تَضِلُّوا السَّبِيلَ
Se o o ri awon ti A fun ni ipin kan ninu tira, ti won n ra isina, ti won si fe ki e sina
وَاللَّهُ أَعْلَمُ بِأَعْدَائِكُمْ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ وَلِيًّا وَكَفَىٰ بِاللَّهِ نَصِيرًا
Allahu si nimo julo nipa awon ota yin. Allahu to ni Alaabo. Allahu si to ni Alaranse
مِنَ الَّذِينَ هَادُوا يُحَرِّفُونَ الْكَلِمَ عَنْ مَوَاضِعِهِ وَيَقُولُونَ سَمِعْنَا وَعَصَيْنَا وَاسْمَعْ غَيْرَ مُسْمَعٍ وَرَاعِنَا لَيًّا بِأَلْسِنَتِهِمْ وَطَعْنًا فِي الدِّينِ ۚ وَلَوْ أَنَّهُمْ قَالُوا سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا وَاسْمَعْ وَانْظُرْنَا لَكَانَ خَيْرًا لَهُمْ وَأَقْوَمَ وَلَٰكِنْ لَعَنَهُمُ اللَّهُ بِكُفْرِهِمْ فَلَا يُؤْمِنُونَ إِلَّا قَلِيلًا
O n be ninu awon yehudi, awon t’o n yi oro pada kuro ni awon aye re, won si n wi pe: “A gbo, a si yapa. Gbo, a o gba tire. Omugo wa.” Won n fi ahon won yi oro sodi ati pe won n bu enu-ate lu esin. ti o ba je pe won so pe: “A gbo, a si tele e. Gbo, ki o si kiye si wa”, iba dara fun won, iba si tona julo. Sugbon Allahu fi won gegun-un nitori aigbagbo won. Nitori naa, won ko nii gbagbo afi die (ninu won)

Choose other languages: