Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #168 Translated in Yoruba

وَرُسُلًا قَدْ قَصَصْنَاهُمْ عَلَيْكَ مِنْ قَبْلُ وَرُسُلًا لَمْ نَقْصُصْهُمْ عَلَيْكَ ۚ وَكَلَّمَ اللَّهُ مُوسَىٰ تَكْلِيمًا
Ati awon Ojise kan ti A ti so itan won fun o siwaju pelu awon Ojise kan ti A ko so itan won fun o. Allahu si ba (Anabi) Musa soro taara
رُسُلًا مُبَشِّرِينَ وَمُنْذِرِينَ لِئَلَّا يَكُونَ لِلنَّاسِ عَلَى اللَّهِ حُجَّةٌ بَعْدَ الرُّسُلِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ عَزِيزًا حَكِيمًا
(A se won ni) Ojise, oniroo idunnu ati olukilo nitori ki awijare ma le wa fun awon eniyan lodo Allahu leyin (ti) awon Ojise (ti jise). Allahu si n je Alagbara, Ologbon
لَٰكِنِ اللَّهُ يَشْهَدُ بِمَا أَنْزَلَ إِلَيْكَ ۖ أَنْزَلَهُ بِعِلْمِهِ ۖ وَالْمَلَائِكَةُ يَشْهَدُونَ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ شَهِيدًا
Sugbon Allahu n jerii si ohun ti O sokale fun o. O so o kale pelu imo Re. Awon molaika naa n jerii (si i). Allahu si to ni Elerii
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَصَدُّوا عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ قَدْ ضَلُّوا ضَلَالًا بَعِيدًا
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won si seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu, won kuku ti sina ni isina t’o jinna
إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَظَلَمُوا لَمْ يَكُنِ اللَّهُ لِيَغْفِرَ لَهُمْ وَلَا لِيَهْدِيَهُمْ طَرِيقًا
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won tun sabosi, Allahu ko nii fori jin won, ko si nii fi oju-ona mo won

Choose other languages: