Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Nisa Ayahs #130 Translated in Yoruba

وَلِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ مُحِيطًا
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si n je Alamotan nipa gbogbo nnkan
وَيَسْتَفْتُونَكَ فِي النِّسَاءِ ۖ قُلِ اللَّهُ يُفْتِيكُمْ فِيهِنَّ وَمَا يُتْلَىٰ عَلَيْكُمْ فِي الْكِتَابِ فِي يَتَامَى النِّسَاءِ اللَّاتِي لَا تُؤْتُونَهُنَّ مَا كُتِبَ لَهُنَّ وَتَرْغَبُونَ أَنْ تَنْكِحُوهُنَّ وَالْمُسْتَضْعَفِينَ مِنَ الْوِلْدَانِ وَأَنْ تَقُومُوا لِلْيَتَامَىٰ بِالْقِسْطِ ۚ وَمَا تَفْعَلُوا مِنْ خَيْرٍ فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ بِهِ عَلِيمًا
Won n bi o leere idajo nipa awon obinrin. So pe: “Allahu l’O n so idajo won fun yin. Ohun ti won n ke fun yin ninu Tira (al-Ƙur’an naa n so idajo fun yin) nipa awon omo-orukan lobinrin ti e ki i fun ni ohun ti won ko fun won (ninu ogun), ti e tun n soju-kokoro lati fe won ati nipa awon alailagbara ninu awon omode (ti e n je ogun won mole.) ati nipa pe ki e duro ti awon omo orukan pelu deede. Ohunkohun ti e ba si se ni rere, dajudaju Allahu n je Onimo nipa re
وَإِنِ امْرَأَةٌ خَافَتْ مِنْ بَعْلِهَا نُشُوزًا أَوْ إِعْرَاضًا فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِمَا أَنْ يُصْلِحَا بَيْنَهُمَا صُلْحًا ۚ وَالصُّلْحُ خَيْرٌ ۗ وَأُحْضِرَتِ الْأَنْفُسُ الشُّحَّ ۚ وَإِنْ تُحْسِنُوا وَتَتَّقُوا فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ بِمَا تَعْمَلُونَ خَبِيرًا
Ti obinrin kan ba paya ise orikunkun tabi ikeyinsi lati odo oko re, ko si ese fun awon mejeeji pe ki won se atunse laaarin ara won. Atunse si dara ju lo. Won si ti fi ahun ati okanjua sise sinu emi eniyan. Ti e ba se rere, ti e si beru (Allahu), dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
وَلَنْ تَسْتَطِيعُوا أَنْ تَعْدِلُوا بَيْنَ النِّسَاءِ وَلَوْ حَرَصْتُمْ ۖ فَلَا تَمِيلُوا كُلَّ الْمَيْلِ فَتَذَرُوهَا كَالْمُعَلَّقَةِ ۚ وَإِنْ تُصْلِحُوا وَتَتَّقُوا فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ غَفُورًا رَحِيمًا
E o le se deede (ninu ife) laaarin awon obinrin, e o baa jerankan re. Nitori naa, e ma se fi sibi kan tan raurau, ki e ma lo pa (eni kan) ti bi ohun agbeko. Ti e ba satunse, ti e si beru (Allahu), dajudaju Allahu n je Alaforijin, Asake-orun
وَإِنْ يَتَفَرَّقَا يُغْنِ اللَّهُ كُلًّا مِنْ سَعَتِهِ ۚ وَكَانَ اللَّهُ وَاسِعًا حَكِيمًا
Ti awon mejeeji ba si pinya, Allahu yoo ro ikini keji loro ninu ola Re t’o gbooro. Allahu si n je Olugbooro (ninu oro), Ologbon

Choose other languages: