Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Naml Ayahs #90 Translated in Yoruba

أَلَمْ يَرَوْا أَنَّا جَعَلْنَا اللَّيْلَ لِيَسْكُنُوا فِيهِ وَالنَّهَارَ مُبْصِرًا ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Se won ko ri i pe dajudaju Awa l’A da oru nitori ki won le sinmi ninu re, (A si da) osan (nitori ki won le) riran? Dajudaju ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo
وَيَوْمَ يُنْفَخُ فِي الصُّورِ فَفَزِعَ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ إِلَّا مَنْ شَاءَ اللَّهُ ۚ وَكُلٌّ أَتَوْهُ دَاخِرِينَ
(Ranti) ojo ti won a fon fere oniwo, gbogbo eni ti o wa ninu sanmo ati ile yo si jaya afi eni ti Allahu ba fe. Gbogbo eda l’o si maa yepere wa ba Allahu
وَتَرَى الْجِبَالَ تَحْسَبُهَا جَامِدَةً وَهِيَ تَمُرُّ مَرَّ السَّحَابِ ۚ صُنْعَ اللَّهِ الَّذِي أَتْقَنَ كُلَّ شَيْءٍ ۚ إِنَّهُ خَبِيرٌ بِمَا تَفْعَلُونَ
O si maa ri awon apata, ti o lero pe nnkan gbagidi t’o duro soju kan naa ni, ti o maa rin irin esujo. (Iyen je) ise Allahu, Eni ti O se gbogbo nnkan ni daadaa. Dajudaju O mo ikoko ohun ti e n se nise
مَنْ جَاءَ بِالْحَسَنَةِ فَلَهُ خَيْرٌ مِنْهَا وَهُمْ مِنْ فَزَعٍ يَوْمَئِذٍ آمِنُونَ
Enikeni ti o ba mu ise rere wa, tire ni rere t’o loore julo si eyi t’o mu wa. Awon si ni olufayabale ninu ijaya ojo yen
وَمَنْ جَاءَ بِالسَّيِّئَةِ فَكُبَّتْ وُجُوهُهُمْ فِي النَّارِ هَلْ تُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كُنْتُمْ تَعْمَلُونَ
Enikeni ti o ba si mu (ise) aburu wa, A si maa da oju won bole ninu Ina. Nje A oo san yin ni esan kan bi ko se ohun ti e n se nise

Choose other languages: