Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Naml Ayahs #63 Translated in Yoruba

قُلِ الْحَمْدُ لِلَّهِ وَسَلَامٌ عَلَىٰ عِبَادِهِ الَّذِينَ اصْطَفَىٰ ۗ آللَّهُ خَيْرٌ أَمَّا يُشْرِكُونَ
So pe: "Gbogbo ope n je ti Allahu. Ki alaafia maa ba awon erusin Re, awon ti O sa lesa. Se Allahu l’O loore julo ni tabi nnkan ti won n so di akegbe Re
أَمَّنْ خَلَقَ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضَ وَأَنْزَلَ لَكُمْ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَنْبَتْنَا بِهِ حَدَائِقَ ذَاتَ بَهْجَةٍ مَا كَانَ لَكُمْ أَنْ تُنْبِتُوا شَجَرَهَا ۗ أَإِلَٰهٌ مَعَ اللَّهِ ۚ بَلْ هُمْ قَوْمٌ يَعْدِلُونَ
(Se iborisa l’o loore julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O da awon sanmo ati ile, ti O so omi kale fun yin lati sanmo, ti A si fi omi naa hu awon ogba oko ti o dara jade? Ko si si agbara fun yin lati mu igi re hu jade. Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Rara, ijo t’o n sebo si Allahu ni won ni
أَمَّنْ جَعَلَ الْأَرْضَ قَرَارًا وَجَعَلَ خِلَالَهَا أَنْهَارًا وَجَعَلَ لَهَا رَوَاسِيَ وَجَعَلَ بَيْنَ الْبَحْرَيْنِ حَاجِزًا ۗ أَإِلَٰهٌ مَعَ اللَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O se ile ni ibugbe, ti O fi awon odo saaarin re, ti O fi awon apata t’o duro sinsin sinu ile, ti O si fi gaga saaarin ibudo mejeeji? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Sibesibe opolopo won ni ko mo
أَمَّنْ يُجِيبُ الْمُضْطَرَّ إِذَا دَعَاهُ وَيَكْشِفُ السُّوءَ وَيَجْعَلُكُمْ خُلَفَاءَ الْأَرْضِ ۗ أَإِلَٰهٌ مَعَ اللَّهِ ۚ قَلِيلًا مَا تَذَكَّرُونَ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O n jepe eni ti ara n ni nigba ti o ba pe E, ti O si maa gbe aburu kuro fun un, ti O si n se yin ni arole lori ile? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Die ni ohun ti e n lo ninu iranti
أَمَّنْ يَهْدِيكُمْ فِي ظُلُمَاتِ الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَمَنْ يُرْسِلُ الرِّيَاحَ بُشْرًا بَيْنَ يَدَيْ رَحْمَتِهِ ۗ أَإِلَٰهٌ مَعَ اللَّهِ ۚ تَعَالَى اللَّهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O n to yin sona ninu awon okunkun ori ile ati inu ibudo, ti O tun n fi ategun ranse ni iro idunnu siwaju ike Re? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Allahu ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I

Choose other languages: