Quran Apps in many lanuages:

Surah An-Naml Ayahs #65 Translated in Yoruba

أَمَّنْ جَعَلَ الْأَرْضَ قَرَارًا وَجَعَلَ خِلَالَهَا أَنْهَارًا وَجَعَلَ لَهَا رَوَاسِيَ وَجَعَلَ بَيْنَ الْبَحْرَيْنِ حَاجِزًا ۗ أَإِلَٰهٌ مَعَ اللَّهِ ۚ بَلْ أَكْثَرُهُمْ لَا يَعْلَمُونَ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O se ile ni ibugbe, ti O fi awon odo saaarin re, ti O fi awon apata t’o duro sinsin sinu ile, ti O si fi gaga saaarin ibudo mejeeji? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Sibesibe opolopo won ni ko mo
أَمَّنْ يُجِيبُ الْمُضْطَرَّ إِذَا دَعَاهُ وَيَكْشِفُ السُّوءَ وَيَجْعَلُكُمْ خُلَفَاءَ الْأَرْضِ ۗ أَإِلَٰهٌ مَعَ اللَّهِ ۚ قَلِيلًا مَا تَذَكَّرُونَ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O n jepe eni ti ara n ni nigba ti o ba pe E, ti O si maa gbe aburu kuro fun un, ti O si n se yin ni arole lori ile? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Die ni ohun ti e n lo ninu iranti
أَمَّنْ يَهْدِيكُمْ فِي ظُلُمَاتِ الْبَرِّ وَالْبَحْرِ وَمَنْ يُرْسِلُ الرِّيَاحَ بُشْرًا بَيْنَ يَدَيْ رَحْمَتِهِ ۗ أَإِلَٰهٌ مَعَ اللَّهِ ۚ تَعَالَى اللَّهُ عَمَّا يُشْرِكُونَ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O n to yin sona ninu awon okunkun ori ile ati inu ibudo, ti O tun n fi ategun ranse ni iro idunnu siwaju ike Re? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? Allahu ga tayo nnkan ti won n fi sebo si I
أَمَّنْ يَبْدَأُ الْخَلْقَ ثُمَّ يُعِيدُهُ وَمَنْ يَرْزُقُكُمْ مِنَ السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ ۗ أَإِلَٰهٌ مَعَ اللَّهِ ۚ قُلْ هَاتُوا بُرْهَانَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
(Se iborisa l’o dara julo ni) tabi (jijosin fun) Eni ti O pile iseda eda, leyin naa, ti O maa da a pada (leyin iku), ti O si n pese fun yin lati sanmo ati ile? Se olohun kan tun wa pelu Allahu ni? So pe: "E mu eri yin wa ti e ba je olododo
قُلْ لَا يَعْلَمُ مَنْ فِي السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ الْغَيْبَ إِلَّا اللَّهُ ۚ وَمَا يَشْعُرُونَ أَيَّانَ يُبْعَثُونَ
So pe: “Awon t’o wa ninu awon sanmo ati ile ko nimo ikoko afi Allahu. Ati pe won ko si mo asiko wo ni A maa gbe awon oku dide.”

Choose other languages: