Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Qasas Ayahs #37 Translated in Yoruba

قَالَ رَبِّ إِنِّي قَتَلْتُ مِنْهُمْ نَفْسًا فَأَخَافُ أَنْ يَقْتُلُونِ
(Anabi Musa) so pe: “Oluwa mi, dajudaju emi pa eni kan ninu won. Nitori naa, mo n beru pe won maa pa mi
وَأَخِي هَارُونُ هُوَ أَفْصَحُ مِنِّي لِسَانًا فَأَرْسِلْهُ مَعِيَ رِدْءًا يُصَدِّقُنِي ۖ إِنِّي أَخَافُ أَنْ يُكَذِّبُونِ
Ati pe arakunrin mi, Harun, o da lahon ju mi lo. Nitori naa, ran an nise pelu mi, ki o je oluranlowo ti yoo maa jerii si ododo oro mi. Dajudaju emi n beru pe won maa pe mi ni opuro.”
قَالَ سَنَشُدُّ عَضُدَكَ بِأَخِيكَ وَنَجْعَلُ لَكُمَا سُلْطَانًا فَلَا يَصِلُونَ إِلَيْكُمَا ۚ بِآيَاتِنَا أَنْتُمَا وَمَنِ اتَّبَعَكُمَا الْغَالِبُونَ
(Allahu) so pe: “A maa fi arakunrin re kun o lowo. A o si fun eyin mejeeji ni agbara, won ko si nii le de odo eyin mejeeji. Pelu awon ami Wa, eyin mejeeji ati awon t’o ba tele eyin mejeeji l’o maa bori.”
فَلَمَّا جَاءَهُمْ مُوسَىٰ بِآيَاتِنَا بَيِّنَاتٍ قَالُوا مَا هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُفْتَرًى وَمَا سَمِعْنَا بِهَٰذَا فِي آبَائِنَا الْأَوَّلِينَ
Nigba ti (Anabi) Musa de ba won pelu awon ami Wa, won wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan adahun. A ko si gbo eyi (ri) laaarin awon baba wa, awon eni akoko.”
وَقَالَ مُوسَىٰ رَبِّي أَعْلَمُ بِمَنْ جَاءَ بِالْهُدَىٰ مِنْ عِنْدِهِ وَمَنْ تَكُونُ لَهُ عَاقِبَةُ الدَّارِ ۖ إِنَّهُ لَا يُفْلِحُ الظَّالِمُونَ
(Anabi) Musa si so pe: “Oluwa mi nimo julo nipa eni ti o mu imona wa lati odo Re ati eni ti atubotan ile (ike) maa je tire. Dajudaju awon alabosi ko nii jere.”

Choose other languages: