Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Mulk Ayahs #19 Translated in Yoruba

هُوَ الَّذِي جَعَلَ لَكُمُ الْأَرْضَ ذَلُولًا فَامْشُوا فِي مَنَاكِبِهَا وَكُلُوا مِنْ رِزْقِهِ ۖ وَإِلَيْهِ النُّشُورُ
Oun ni Eni ti O ro ile fun yin. Nitori naa, e rin ni awon agbegbe re kaakiri, ki e si je ninu arisiki Re. Odo Re si ni ajinde eda wa
أَأَمِنْتُمْ مَنْ فِي السَّمَاءِ أَنْ يَخْسِفَ بِكُمُ الْأَرْضَ فَإِذَا هِيَ تَمُورُ
Se e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le je ki ile gbe yin mi? Nigba naa, ile yo si maa mi titi
أَمْ أَمِنْتُمْ مَنْ فِي السَّمَاءِ أَنْ يُرْسِلَ عَلَيْكُمْ حَاصِبًا ۖ فَسَتَعْلَمُونَ كَيْفَ نَذِيرِ
Tabi e fokanbale si Eni ti O wa ni (oke) sanmo pe ko le fi okuta ina ranse si yin ni? Nigba naa, e si maa mo bi ikilo Mi ti ri
وَلَقَدْ كَذَّبَ الَّذِينَ مِنْ قَبْلِهِمْ فَكَيْفَ كَانَ نَكِيرِ
Awon t’o siwaju won kuku pe ododo niro. Bawo si ni bi Mo se (fi iya) ko (aburu fun won) ti ri
أَوَلَمْ يَرَوْا إِلَى الطَّيْرِ فَوْقَهُمْ صَافَّاتٍ وَيَقْبِضْنَ ۚ مَا يُمْسِكُهُنَّ إِلَّا الرَّحْمَٰنُ ۚ إِنَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ بَصِيرٌ
Se won ko ri awon eye ti o wa ni oke won, ti (won) n na iye apa (won), ti won si n pa a mora? Kini kan ko mu won duro (sinu ofurufu) afi Ajoke-aye. Dajudaju Oun si ni Oluriran nipa gbogbo nnkan

Choose other languages: