Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #12 Translated in Yoruba

5:8
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا كُونُوا قَوَّامِينَ لِلَّهِ شُهَدَاءَ بِالْقِسْطِ ۖ وَلَا يَجْرِمَنَّكُمْ شَنَآنُ قَوْمٍ عَلَىٰ أَلَّا تَعْدِلُوا ۚ اعْدِلُوا هُوَ أَقْرَبُ لِلتَّقْوَىٰ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ خَبِيرٌ بِمَا تَعْمَلُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, nitori ti Allahu e je oluduro sinsin lori ododo nigba ti e ba n jerii. E ma se je ki ikorira awon eniyan kan ti yin lati ma se deede. E se deede, ohun l’o sunmo iberu Allahu julo. Ki e si beru Allahu. Dajudaju Allahu ni Alamotan nipa ohun ti e n se nise
5:9
وَعَدَ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ ۙ لَهُمْ مَغْفِرَةٌ وَأَجْرٌ عَظِيمٌ
Allahu se adehun fun awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si sise rere (pe) aforijin ati esan nla n be fun won
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا أُولَٰئِكَ أَصْحَابُ الْجَحِيمِ
Awon t’o sai gbagbo, ti won si pe awon ayah Wa niro, awon wonyen ni ero inu ina Jehim
يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا اذْكُرُوا نِعْمَتَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ هَمَّ قَوْمٌ أَنْ يَبْسُطُوا إِلَيْكُمْ أَيْدِيَهُمْ فَكَفَّ أَيْدِيَهُمْ عَنْكُمْ ۖ وَاتَّقُوا اللَّهَ ۚ وَعَلَى اللَّهِ فَلْيَتَوَكَّلِ الْمُؤْمِنُونَ
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ranti idera ti Allahu se fun yin; nigba ti ijo kan gbero lati nawo ija si yin, (Allahu) si ko won lowo ro fun yin. E beru Allahu. Ati pe Allahu ni ki awon onigbagbo ododo gbarale
وَلَقَدْ أَخَذَ اللَّهُ مِيثَاقَ بَنِي إِسْرَائِيلَ وَبَعَثْنَا مِنْهُمُ اثْنَيْ عَشَرَ نَقِيبًا ۖ وَقَالَ اللَّهُ إِنِّي مَعَكُمْ ۖ لَئِنْ أَقَمْتُمُ الصَّلَاةَ وَآتَيْتُمُ الزَّكَاةَ وَآمَنْتُمْ بِرُسُلِي وَعَزَّرْتُمُوهُمْ وَأَقْرَضْتُمُ اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا لَأُكَفِّرَنَّ عَنْكُمْ سَيِّئَاتِكُمْ وَلَأُدْخِلَنَّكُمْ جَنَّاتٍ تَجْرِي مِنْ تَحْتِهَا الْأَنْهَارُ ۚ فَمَنْ كَفَرَ بَعْدَ ذَٰلِكَ مِنْكُمْ فَقَدْ ضَلَّ سَوَاءَ السَّبِيلِ
Dajudaju Allahu gba adehun lowo awon omo ’Isro’il. A si gbe ijoye mejila dide ninu won. Allahu si so fun won pe: “Dajudaju Mo n be pelu yin, ti e ba n kirun, ti e ba n yo Zakah, ti e ba n gba awon Ojise Mi gbo, ti e ba n ran won lowo, ti e ba n ya Allahu ni dukia t’o dara. Dajudaju Mo maa pa awon asise yin re. Dajudaju Mo maa mu yin wo inu awon Ogba Idera kan, ti odo n san ni isale re. Amo enikeni ti o ba sai gbagbo leyin iyen ninu yin, o ti sina kuro loju ona.”

Choose other languages: