Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #21 Translated in Yoruba

لَقَدْ كَفَرَ الَّذِينَ قَالُوا إِنَّ اللَّهَ هُوَ الْمَسِيحُ ابْنُ مَرْيَمَ ۚ قُلْ فَمَنْ يَمْلِكُ مِنَ اللَّهِ شَيْئًا إِنْ أَرَادَ أَنْ يُهْلِكَ الْمَسِيحَ ابْنَ مَرْيَمَ وَأُمَّهُ وَمَنْ فِي الْأَرْضِ جَمِيعًا ۗ وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۚ يَخْلُقُ مَا يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Won kuku ti di keferi, awon t’o wi pe: “Dajudaju Allahu ni Mosih omo Moryam.” So pe: “Ta si l’o ni ikapa kini kan lodo Allahu ti (Allahu) ba fe pa Mosih omo Moryam, ati iya re ati awon t’o n be lori ile aye run patapata?” Ti Allahu ni ijoba awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. (Allahu) n sedaa ohunkohun ti O ba fe. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
وَقَالَتِ الْيَهُودُ وَالنَّصَارَىٰ نَحْنُ أَبْنَاءُ اللَّهِ وَأَحِبَّاؤُهُ ۚ قُلْ فَلِمَ يُعَذِّبُكُمْ بِذُنُوبِكُمْ ۖ بَلْ أَنْتُمْ بَشَرٌ مِمَّنْ خَلَقَ ۚ يَغْفِرُ لِمَنْ يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَلِلَّهِ مُلْكُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ وَمَا بَيْنَهُمَا ۖ وَإِلَيْهِ الْمَصِيرُ
Awon yehudi ati nasara wi pe: "Awa ni omo Allahu ati ololufe Re." So pe: “Ki ni idi ti O se n fi iya ese yin je yin nigba naa?” Rara (ko ri bi e se wi, amo) abara ni yin ninu awon ti O seda. O n saforijin fun eni ti O ba fe. O si n je eni ti O ba fe niya. Ti Allahu ni ijoba awon sanmo, ile ati ohunkohun ti n be laaarin awon mejeeji. Odo Re si ni abo eda
يَا أَهْلَ الْكِتَابِ قَدْ جَاءَكُمْ رَسُولُنَا يُبَيِّنُ لَكُمْ عَلَىٰ فَتْرَةٍ مِنَ الرُّسُلِ أَنْ تَقُولُوا مَا جَاءَنَا مِنْ بَشِيرٍ وَلَا نَذِيرٍ ۖ فَقَدْ جَاءَكُمْ بَشِيرٌ وَنَذِيرٌ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Eyin ahlul-kitab, dajudaju Ojise Wa ti de ba yin, ti o n se alaye (oro) fun yin leyin asiko ti A ti da awon Ojise duro, nitori ki e ma baa wi pe: “Ko si oniroo idunnu tabi olukilo kan ti o de ba wa.” Nitori naa, dajudaju oniroo idunnu ati olukilo kan ti de ba yin. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
وَإِذْ قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ يَا قَوْمِ اذْكُرُوا نِعْمَةَ اللَّهِ عَلَيْكُمْ إِذْ جَعَلَ فِيكُمْ أَنْبِيَاءَ وَجَعَلَكُمْ مُلُوكًا وَآتَاكُمْ مَا لَمْ يُؤْتِ أَحَدًا مِنَ الْعَالَمِينَ
Nigba ti (Anabi) Musa so fun ijo re pe: "Eyin ijo mi, e ranti idera ti Allahu se fun yin, nigba ti O fi awon Anabi saaarin yin, ti O se yin ni oba, ti O tun fun yin ni nnkan ti ko fun eni kan ri ni agbaye (lasiko tiyin)
يَا قَوْمِ ادْخُلُوا الْأَرْضَ الْمُقَدَّسَةَ الَّتِي كَتَبَ اللَّهُ لَكُمْ وَلَا تَرْتَدُّوا عَلَىٰ أَدْبَارِكُمْ فَتَنْقَلِبُوا خَاسِرِينَ
Eyin ijo mi, e wo ori ile mimo ti Allahu ko mo yin. E ma se pada seyin, nitori ki e ma baa pada di eni ofo

Choose other languages: