Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Maeda Ayahs #114 Translated in Yoruba

إِذْ قَالَ اللَّهُ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ اذْكُرْ نِعْمَتِي عَلَيْكَ وَعَلَىٰ وَالِدَتِكَ إِذْ أَيَّدْتُكَ بِرُوحِ الْقُدُسِ تُكَلِّمُ النَّاسَ فِي الْمَهْدِ وَكَهْلًا ۖ وَإِذْ عَلَّمْتُكَ الْكِتَابَ وَالْحِكْمَةَ وَالتَّوْرَاةَ وَالْإِنْجِيلَ ۖ وَإِذْ تَخْلُقُ مِنَ الطِّينِ كَهَيْئَةِ الطَّيْرِ بِإِذْنِي فَتَنْفُخُ فِيهَا فَتَكُونُ طَيْرًا بِإِذْنِي ۖ وَتُبْرِئُ الْأَكْمَهَ وَالْأَبْرَصَ بِإِذْنِي ۖ وَإِذْ تُخْرِجُ الْمَوْتَىٰ بِإِذْنِي ۖ وَإِذْ كَفَفْتُ بَنِي إِسْرَائِيلَ عَنْكَ إِذْ جِئْتَهُمْ بِالْبَيِّنَاتِ فَقَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا مِنْهُمْ إِنْ هَٰذَا إِلَّا سِحْرٌ مُبِينٌ
(Ranti) nigba ti Allahu so pe: “‘Isa omo Moryam, ranti idera Mi lori re ati lori iya re, nigba ti Mo fi emi Mimo (molaika Jibril) ran o lowo, ti o si n ba awon eniyan soro lori ite ni oponlo ati nigba ti o dagba. (Ranti) nigba ti Mo fun o ni imo Tira, ijinle oye, at-Taorah ati al-’Injil. (Ranti) nigba ti o n mo nnkan lati inu amo bi irisi eye, ti o n fe ategun sinu re, ti o n di eye pelu iyonda Mi. O n wo afoju ati adete san pelu iyonda. (Ranti) nigba ti o n mu awon oku jade (ni alaaye lati inu saree) pelu iyonda Mi. (Ranti) nigba ti Mo ko awon omo ’Isro’il lowo ro, nigba ti o mu awon eri t’o yanju wa ba won. Awon t’o sai gbagbo ninu won si wi pe: “Ki ni eyi bi ko se idan ponnbele.”
وَإِذْ أَوْحَيْتُ إِلَى الْحَوَارِيِّينَ أَنْ آمِنُوا بِي وَبِرَسُولِي قَالُوا آمَنَّا وَاشْهَدْ بِأَنَّنَا مُسْلِمُونَ
(Ranti) nigba ti Mo fi mo awon omoleyin re ninu okan won pe ki won gbagbo ninu Emi ati Ojise Mi. Won so pe: “A gbagbo. Ki o si jerii pe dajudaju musulumi ni wa.”
إِذْ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ يَا عِيسَى ابْنَ مَرْيَمَ هَلْ يَسْتَطِيعُ رَبُّكَ أَنْ يُنَزِّلَ عَلَيْنَا مَائِدَةً مِنَ السَّمَاءِ ۖ قَالَ اتَّقُوا اللَّهَ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
(Ranti) nigba ti awon omoleyin re so pe: “‘Isa omo Moryam, nje Oluwa re le so opon ounje kan kale lati sanmo?” O so pe: "E beru Allahu ti e ba je onigbagbo ododo
قَالُوا نُرِيدُ أَنْ نَأْكُلَ مِنْهَا وَتَطْمَئِنَّ قُلُوبُنَا وَنَعْلَمَ أَنْ قَدْ صَدَقْتَنَا وَنَكُونَ عَلَيْهَا مِنَ الشَّاهِدِينَ
Won so pe: “A fe je ninu re, a si fe ki okan wa bale, ki a si le mo pe o ti so ododo fun wa. A si maa wa ninu awon olujerii.”
قَالَ عِيسَى ابْنُ مَرْيَمَ اللَّهُمَّ رَبَّنَا أَنْزِلْ عَلَيْنَا مَائِدَةً مِنَ السَّمَاءِ تَكُونُ لَنَا عِيدًا لِأَوَّلِنَا وَآخِرِنَا وَآيَةً مِنْكَ ۖ وَارْزُقْنَا وَأَنْتَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ
‘Isa omo Moryam so pe: "Allahu, Oluwa wa, so opon ounje kan kale fun wa lati inu sanmo, ki o je odun fun eni akoko wa ati eni ikeyin wa.1 Ki o si je ami kan lati odo Re. Pese fun wa, Iwo si loore julo ninu awon olupese

Choose other languages: