Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Kahf Ayahs #20 Translated in Yoruba

وَإِذِ اعْتَزَلْتُمُوهُمْ وَمَا يَعْبُدُونَ إِلَّا اللَّهَ فَأْوُوا إِلَى الْكَهْفِ يَنْشُرْ لَكُمْ رَبُّكُمْ مِنْ رَحْمَتِهِ وَيُهَيِّئْ لَكُمْ مِنْ أَمْرِكُمْ مِرْفَقًا
(Awon odokunrin naa so funra won pe:) nigba ti e ba yera fun awon ati nnkan ti won n josin fun leyin Allahu, ti e si wa ibugbe sinu iho apata, Oluwa yin yoo te ninu ike Re sile fun yin. O si maa se oro yin ni irorun fun yin
وَتَرَى الشَّمْسَ إِذَا طَلَعَتْ تَزَاوَرُ عَنْ كَهْفِهِمْ ذَاتَ الْيَمِينِ وَإِذَا غَرَبَتْ تَقْرِضُهُمْ ذَاتَ الشِّمَالِ وَهُمْ فِي فَجْوَةٍ مِنْهُ ۚ ذَٰلِكَ مِنْ آيَاتِ اللَّهِ ۗ مَنْ يَهْدِ اللَّهُ فَهُوَ الْمُهْتَدِ ۖ وَمَنْ يُضْلِلْ فَلَنْ تَجِدَ لَهُ وَلِيًّا مُرْشِدًا
O maa ri oorun nigba ti o ba yo, o maa yeba kuro nibi iho won si owo otun. Nigba ti o ba tun wo, o maa fi won sile si owo osi. Won si wa ninu aye ti o feju ninu iho apata. Iyen wa ninu awon ami Allahu. Enikeni ti Allahu ba fi mona (’Islam), oun ni olumona. Enikeni ti O ba si lona, o o si nii ri oluranlowo atoni-sona kan fun un
وَتَحْسَبُهُمْ أَيْقَاظًا وَهُمْ رُقُودٌ ۚ وَنُقَلِّبُهُمْ ذَاتَ الْيَمِينِ وَذَاتَ الشِّمَالِ ۖ وَكَلْبُهُمْ بَاسِطٌ ذِرَاعَيْهِ بِالْوَصِيدِ ۚ لَوِ اطَّلَعْتَ عَلَيْهِمْ لَوَلَّيْتَ مِنْهُمْ فِرَارًا وَلَمُلِئْتَ مِنْهُمْ رُعْبًا
O maa lero pe won laju sile ni, oju oorun ni won si wa. A si n yi won legbee pada sotun-un sosi. Aja won si na apa re mejeeji sile ni gbagede apata. Ti o ba je pe o yoju wo won ni, iwo iba peyin da lati ho fun won, iwo iba si kun fun iberu-bojo lati ara won
وَكَذَٰلِكَ بَعَثْنَاهُمْ لِيَتَسَاءَلُوا بَيْنَهُمْ ۚ قَالَ قَائِلٌ مِنْهُمْ كَمْ لَبِثْتُمْ ۖ قَالُوا لَبِثْنَا يَوْمًا أَوْ بَعْضَ يَوْمٍ ۚ قَالُوا رَبُّكُمْ أَعْلَمُ بِمَا لَبِثْتُمْ فَابْعَثُوا أَحَدَكُمْ بِوَرِقِكُمْ هَٰذِهِ إِلَى الْمَدِينَةِ فَلْيَنْظُرْ أَيُّهَا أَزْكَىٰ طَعَامًا فَلْيَأْتِكُمْ بِرِزْقٍ مِنْهُ وَلْيَتَلَطَّفْ وَلَا يُشْعِرَنَّ بِكُمْ أَحَدًا
Bayen (ni won wa) ti A fi gbe won dide pada nitori ki won le bi ara won leere ibeere. Onsoro kan ninu won so pe: “Igba wo le ti wa nibi?” Won so pe: “A wa nibi fun ojo kan tabi idaji ojo.” Won so pe: “Oluwa yin nimo julo nipa igba ti e ti wa nibi.” Nitori naa, e gbe okan ninu yin dide lo si inu ilu pelu owo fadaka yin yii. Ki o wo ewo ninu ounje ilu l’o mo julo, ki o si mu ase wa fun yin ninu re. Ki o se pelepele, ko si gbodo je ki eni kan kan fura si yin
إِنَّهُمْ إِنْ يَظْهَرُوا عَلَيْكُمْ يَرْجُمُوكُمْ أَوْ يُعِيدُوكُمْ فِي مِلَّتِهِمْ وَلَنْ تُفْلِحُوا إِذًا أَبَدًا
(Nitori pe) dajudaju ti won ba fi le mo nipa yin, won yoo ju yin loko tabi ki won da yin pada sinu esin won. (Ti o ba si fi ri bee) e o nii jere mo laelae niyen

Choose other languages: