Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #46 Translated in Yoruba

قُلْ لَوْ كَانَ مَعَهُ آلِهَةٌ كَمَا يَقُولُونَ إِذًا لَابْتَغَوْا إِلَىٰ ذِي الْعَرْشِ سَبِيلًا
So pe: “Ti o ba je pe awon olohun kan tun wa pelu Re gege bi won se n wi, won iba wa ona lati sunmo (Allahu) Onitee-ola ni.”
سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يَقُولُونَ عُلُوًّا كَبِيرًا
Mimo ni fun Un. O si ga ni giga t’o tobi tayo ohun ti won n wi (ni aida nipa Re)
تُسَبِّحُ لَهُ السَّمَاوَاتُ السَّبْعُ وَالْأَرْضُ وَمَنْ فِيهِنَّ ۚ وَإِنْ مِنْ شَيْءٍ إِلَّا يُسَبِّحُ بِحَمْدِهِ وَلَٰكِنْ لَا تَفْقَهُونَ تَسْبِيحَهُمْ ۗ إِنَّهُ كَانَ حَلِيمًا غَفُورًا
Awon sanmo mejeeje, ile ati awon ti won wa ninu won n se afomo fun Un. Ko si si kini kan afi ki o se afomo ati idupe fun Un. Sugbon e ko le gbo agboye afomo won. Dajudaju Allahu n je Alafarada, Alaforijin
وَإِذَا قَرَأْتَ الْقُرْآنَ جَعَلْنَا بَيْنَكَ وَبَيْنَ الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ حِجَابًا مَسْتُورًا
Nigba ti o ba n ke al-Ƙur’an, A maa fi gaga aabo saaarin iwo ati awon ti ko gba Ojo Ikeyin gbo
وَجَعَلْنَا عَلَىٰ قُلُوبِهِمْ أَكِنَّةً أَنْ يَفْقَهُوهُ وَفِي آذَانِهِمْ وَقْرًا ۚ وَإِذَا ذَكَرْتَ رَبَّكَ فِي الْقُرْآنِ وَحْدَهُ وَلَّوْا عَلَىٰ أَدْبَارِهِمْ نُفُورًا
A fi ebibo bo okan won nitori ki won ma baa gbo o ye. (A tun fi) edidi sinu eti won. Nigba ti o ba si daruko Oluwa re nikan soso ninu al-Ƙur’an, won maa peyin won da lati sa lo

Choose other languages: