Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #5 Translated in Yoruba

سُبْحَانَ الَّذِي أَسْرَىٰ بِعَبْدِهِ لَيْلًا مِنَ الْمَسْجِدِ الْحَرَامِ إِلَى الْمَسْجِدِ الْأَقْصَى الَّذِي بَارَكْنَا حَوْلَهُ لِنُرِيَهُ مِنْ آيَاتِنَا ۚ إِنَّهُ هُوَ السَّمِيعُ الْبَصِيرُ
Mimo ni fun Eni ti O mu erusin Re se irin-ajo ni ale lati Mosalasi Haram si Mosalasi Aƙso ti A fi ibukun yi ka, nitori ki A le fi ninu awon ami Wa han an. Dajudaju Allahu, Oun ni Olugbo, Oluriran
وَآتَيْنَا مُوسَى الْكِتَابَ وَجَعَلْنَاهُ هُدًى لِبَنِي إِسْرَائِيلَ أَلَّا تَتَّخِذُوا مِنْ دُونِي وَكِيلًا
A fun (Anabi) Musa ni Tira. A si se e ni imona fun awon omo ’Isro’il. (A si so) pe: “E ma se mu alaabo kan leyin Mi.”
ذُرِّيَّةَ مَنْ حَمَلْنَا مَعَ نُوحٍ ۚ إِنَّهُ كَانَ عَبْدًا شَكُورًا
(E je) aromodomo awon ti A gbe gun oko oju-omi pelu (Anabi) Nuh. Dajudaju (Nuh) je erusin, oludupe
وَقَضَيْنَا إِلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ فِي الْكِتَابِ لَتُفْسِدُنَّ فِي الْأَرْضِ مَرَّتَيْنِ وَلَتَعْلُنَّ عُلُوًّا كَبِيرًا
A si fi mo awon omo ’Isro’il ninu Tira pe: “Dajudaju e maa sebaje lori ile nigba meji. Dajudaju e tun maa segberaga t’o tobi.”
فَإِذَا جَاءَ وَعْدُ أُولَاهُمَا بَعَثْنَا عَلَيْكُمْ عِبَادًا لَنَا أُولِي بَأْسٍ شَدِيدٍ فَجَاسُوا خِلَالَ الدِّيَارِ ۚ وَكَانَ وَعْدًا مَفْعُولًا
Nitori naa, nigba ti adehun fun akoko ninu mejeeji ba sele, A maa gbe awon erusin Wa kan, ti won lagbara gan-an, dide si yin. Won yoo da rogbodiyan sile laaarin ilu (yin). O je adehun kan ti A maa mu se

Choose other languages: