Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Isra Ayahs #15 Translated in Yoruba

وَيَدْعُ الْإِنْسَانُ بِالشَّرِّ دُعَاءَهُ بِالْخَيْرِ ۖ وَكَانَ الْإِنْسَانُ عَجُولًا
Eniyan n toro aburu bi o se n toro ohun rere; eniyan si je olukanju
وَجَعَلْنَا اللَّيْلَ وَالنَّهَارَ آيَتَيْنِ ۖ فَمَحَوْنَا آيَةَ اللَّيْلِ وَجَعَلْنَا آيَةَ النَّهَارِ مُبْصِرَةً لِتَبْتَغُوا فَضْلًا مِنْ رَبِّكُمْ وَلِتَعْلَمُوا عَدَدَ السِّنِينَ وَالْحِسَابَ ۚ وَكُلَّ شَيْءٍ فَصَّلْنَاهُ تَفْصِيلًا
A se ale ati osan ni ami meji; A pa ami ale re, A si se ami osan ni iriran1 nitori ki e le wa oore ajulo lati odo Oluwa yin ati nitori ki e le mo onka awon odun ati isiro. Gbogbo nnkan ni A ti salaye re ni ifosiwewe
وَكُلَّ إِنْسَانٍ أَلْزَمْنَاهُ طَائِرَهُ فِي عُنُقِهِ ۖ وَنُخْرِجُ لَهُ يَوْمَ الْقِيَامَةِ كِتَابًا يَلْقَاهُ مَنْشُورًا
Eniyan kookan ni A ti la ayanmo ati iwe ise re bo lorun. A si maa mu iwe kan jade fun un ni Ojo Ajinde. O maa pade re ni sisi sile
اقْرَأْ كِتَابَكَ كَفَىٰ بِنَفْسِكَ الْيَوْمَ عَلَيْكَ حَسِيبًا
Ka iwe (ise) re. Iwo ti to ni olusiro fun emi ara re lonii
مَنِ اهْتَدَىٰ فَإِنَّمَا يَهْتَدِي لِنَفْسِهِ ۖ وَمَنْ ضَلَّ فَإِنَّمَا يَضِلُّ عَلَيْهَا ۚ وَلَا تَزِرُ وَازِرَةٌ وِزْرَ أُخْرَىٰ ۗ وَمَا كُنَّا مُعَذِّبِينَ حَتَّىٰ نَبْعَثَ رَسُولًا
Enikeni t’o ba mona, o mona fun emi ara re. Enikeni t’o ba si sina, o n sina fun emi ara re. Eleru-ese kan ko nii ru ese elomiiran. A o si nii je awon eda niya titi A fi maa gbe ojise kan dide (si won)

Choose other languages: