Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Insan Ayahs #21 Translated in Yoruba

وَيُسْقَوْنَ فِيهَا كَأْسًا كَانَ مِزَاجُهَا زَنْجَبِيلًا
Ati pe won yoo maa fun won ni ife oti kan mu ninu (Ogba Idera). Ohun ti A popo mo (oti naa) ni atale
عَيْنًا فِيهَا تُسَمَّىٰ سَلْسَبِيلًا
Ninu Ogba Idera (won yoo tun maa mu) omi iseleru kan, ti A n pe ni omi salsabil
وَيَطُوفُ عَلَيْهِمْ وِلْدَانٌ مُخَلَّدُونَ إِذَا رَأَيْتَهُمْ حَسِبْتَهُمْ لُؤْلُؤًا مَنْثُورًا
Awon odokunrin ti ko nii gbo yo si maa lo bo laaarin won. Nigba ti iwo ba si ri won, iwo yoo ka won kun okuta olowo iyebiye ti won tan kale
وَإِذَا رَأَيْتَ ثَمَّ رَأَيْتَ نَعِيمًا وَمُلْكًا كَبِيرًا
Nigba ti iwo ba si wo ibe yen (ninu Ogba Idera), iwo yoo ri idera ati ola t’o tobi
عَالِيَهُمْ ثِيَابُ سُنْدُسٍ خُضْرٌ وَإِسْتَبْرَقٌ ۖ وَحُلُّوا أَسَاوِرَ مِنْ فِضَّةٍ وَسَقَاهُمْ رَبُّهُمْ شَرَابًا طَهُورًا
Aso ara won ni aso aran felefele alawo eweko ati aso alagbaaa. A si maa fi egba-owo onifadaka se won ni oso. Oluwa won yo si fun won ni ohun mimu mimo mu

Choose other languages: