Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hujraat Ayahs #17 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا النَّاسُ إِنَّا خَلَقْنَاكُمْ مِنْ ذَكَرٍ وَأُنْثَىٰ وَجَعَلْنَاكُمْ شُعُوبًا وَقَبَائِلَ لِتَعَارَفُوا ۚ إِنَّ أَكْرَمَكُمْ عِنْدَ اللَّهِ أَتْقَاكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَلِيمٌ خَبِيرٌ
Eyin eniyan, dajudaju Awa seda yin lati ara okunrin ati obinrin. A si se yin ni orile-ede orile-ede ati iran-iran nitori ki e le dara yin mo. Dajudaju alapon-onle julo ninu yin lodo Allahu ni eni t’o beru (Re) julo. Dajudaju Allahu ni Onimo, Alamotan
قَالَتِ الْأَعْرَابُ آمَنَّا ۖ قُلْ لَمْ تُؤْمِنُوا وَلَٰكِنْ قُولُوا أَسْلَمْنَا وَلَمَّا يَدْخُلِ الْإِيمَانُ فِي قُلُوبِكُمْ ۖ وَإِنْ تُطِيعُوا اللَّهَ وَرَسُولَهُ لَا يَلِتْكُمْ مِنْ أَعْمَالِكُمْ شَيْئًا ۚ إِنَّ اللَّهَ غَفُورٌ رَحِيمٌ
Awon Larubawa oko so pe: "A gbagbo ni ododo." So pe: "Eyin ko gbagbo ni ododo." Sugbon e so pe: "A gba ’Islam." niwon igba ti igbagbo ododo ko ti i wo’nu okan yin. Ti e ba tele (ase) Allahu ati Ojise Re, (Allahu) ko nii din kini kan ku fun yin ninu (esan) awon ise yin. Dajudaju Allahu ni Alaforijin, Asake-orun
إِنَّمَا الْمُؤْمِنُونَ الَّذِينَ آمَنُوا بِاللَّهِ وَرَسُولِهِ ثُمَّ لَمْ يَرْتَابُوا وَجَاهَدُوا بِأَمْوَالِهِمْ وَأَنْفُسِهِمْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۚ أُولَٰئِكَ هُمُ الصَّادِقُونَ
Awon onigbagbo ododo ni awon t’o gbagbo ninu Allahu ati Ojise Re, leyin naa ti won ko seyemeji, ti won si fi dukia won ati emi won jagun fun esin Allahu. Awon wonyen, awon ni olododo
قُلْ أَتُعَلِّمُونَ اللَّهَ بِدِينِكُمْ وَاللَّهُ يَعْلَمُ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۚ وَاللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
So pe: "Se e maa ko Allahu ni esin yin ni?" Allahu si mo ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan
يَمُنُّونَ عَلَيْكَ أَنْ أَسْلَمُوا ۖ قُلْ لَا تَمُنُّوا عَلَيَّ إِسْلَامَكُمْ ۖ بَلِ اللَّهُ يَمُنُّ عَلَيْكُمْ أَنْ هَدَاكُمْ لِلْإِيمَانِ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
Won n seregun lori re pe won gba ’Islam. So pe: "E ma fi ’Islam yin seregun lori mi.” Bee ni! Allahu l’O maa seregun lori yin pe O fi yin mona sibi igbagbo ododo ti e ba je olododo

Choose other languages: