Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #58 Translated in Yoruba

وَلِيَعْلَمَ الَّذِينَ أُوتُوا الْعِلْمَ أَنَّهُ الْحَقُّ مِنْ رَبِّكَ فَيُؤْمِنُوا بِهِ فَتُخْبِتَ لَهُ قُلُوبُهُمْ ۗ وَإِنَّ اللَّهَ لَهَادِ الَّذِينَ آمَنُوا إِلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ
(Eyi n sele) nitori ki awon ti A fun ni imo le mo pe dajudaju al- Ƙur’an je ododo lati odo Oluwa re. Nitori naa, won yo si gbagbo ninu re, okan won yo si bale si i. Dajudaju Allahu l’O n fi ese awon t’o gbagbo ni ododo rinle soju ona taara (’Islam)
وَلَا يَزَالُ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي مِرْيَةٍ مِنْهُ حَتَّىٰ تَأْتِيَهُمُ السَّاعَةُ بَغْتَةً أَوْ يَأْتِيَهُمْ عَذَابُ يَوْمٍ عَقِيمٍ
Awon t’o sai gbagbo ko si nii ye wa ninu iyemeji nipa re titi Akoko naa yoo fi de ba won ni ojiji tabi (titi) iya ojo iparun yoo fi de ba won
الْمُلْكُ يَوْمَئِذٍ لِلَّهِ يَحْكُمُ بَيْنَهُمْ ۚ فَالَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ فِي جَنَّاتِ النَّعِيمِ
Gbogbo ijoba ojo yen n je ti Allahu ti O maa sedajo laaarin won. Nitori naa, awon t’o gbagbo ni ododo, ti won si se awon ise rere, (won yoo wa) ninu awon Ogba Idera
وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا فَأُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مُهِينٌ
Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro; awon wonyen ni iya ti i yepere eda si wa fun
وَالَّذِينَ هَاجَرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ ثُمَّ قُتِلُوا أَوْ مَاتُوا لَيَرْزُقَنَّهُمُ اللَّهُ رِزْقًا حَسَنًا ۚ وَإِنَّ اللَّهَ لَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ
Awon ti won gbe ilu won ju sile nitori esin Allahu, leyin naa, ti won pa won tabi ti won ku; dajudaju Allahu yoo pese fun won ni ipese t’o dara. Dajudaju Allahu, O ma l’oore julo ninu awon olupese

Choose other languages: