Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #61 Translated in Yoruba

وَالَّذِينَ كَفَرُوا وَكَذَّبُوا بِآيَاتِنَا فَأُولَٰئِكَ لَهُمْ عَذَابٌ مُهِينٌ
Awon t’o si sai gbagbo, ti won tun pe awon ayah Wa niro; awon wonyen ni iya ti i yepere eda si wa fun
وَالَّذِينَ هَاجَرُوا فِي سَبِيلِ اللَّهِ ثُمَّ قُتِلُوا أَوْ مَاتُوا لَيَرْزُقَنَّهُمُ اللَّهُ رِزْقًا حَسَنًا ۚ وَإِنَّ اللَّهَ لَهُوَ خَيْرُ الرَّازِقِينَ
Awon ti won gbe ilu won ju sile nitori esin Allahu, leyin naa, ti won pa won tabi ti won ku; dajudaju Allahu yoo pese fun won ni ipese t’o dara. Dajudaju Allahu, O ma l’oore julo ninu awon olupese
لَيُدْخِلَنَّهُمْ مُدْخَلًا يَرْضَوْنَهُ ۗ وَإِنَّ اللَّهَ لَعَلِيمٌ حَلِيمٌ
Dajudaju (Allahu) yoo fi won si aye kan ti won yoo yonu si. Dajudaju Allahu ma ni Onimo, Alafarada
ذَٰلِكَ وَمَنْ عَاقَبَ بِمِثْلِ مَا عُوقِبَ بِهِ ثُمَّ بُغِيَ عَلَيْهِ لَيَنْصُرَنَّهُ اللَّهُ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَعَفُوٌّ غَفُورٌ
Iyen (niyen). Enikeni ti o ba si gbesan iru iya ti won fi je e, leyin naa ti won ba tun sabosi si i, dajudaju Allahu yoo saranse fun un. Dajudaju Allahu ma ni Alamojuukuro, Alaforijin
ذَٰلِكَ بِأَنَّ اللَّهَ يُولِجُ اللَّيْلَ فِي النَّهَارِ وَيُولِجُ النَّهَارَ فِي اللَّيْلِ وَأَنَّ اللَّهَ سَمِيعٌ بَصِيرٌ
Iyen nitori pe dajudaju Allahu n fi oru bo inu osan, O si n fi osan bo inu oru. Allahu si ni Olugbo, Oluriran

Choose other languages: