Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #40 Translated in Yoruba

وَالْبُدْنَ جَعَلْنَاهَا لَكُمْ مِنْ شَعَائِرِ اللَّهِ لَكُمْ فِيهَا خَيْرٌ ۖ فَاذْكُرُوا اسْمَ اللَّهِ عَلَيْهَا صَوَافَّ ۖ فَإِذَا وَجَبَتْ جُنُوبُهَا فَكُلُوا مِنْهَا وَأَطْعِمُوا الْقَانِعَ وَالْمُعْتَرَّ ۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرْنَاهَا لَكُمْ لَعَلَّكُمْ تَشْكُرُونَ
Awon rakunmi, A se won ninu awon nnkan arisami fun esin Allahu fun yin. Oore wa lara won fun yin. Nitori naa, e daruko Allahu le won lori (ki e si gun won) ni iduro. Nigba ti won ba fi egbe lele, e je ninu re. E fi bo oniteelorun ati atoroje. Bayen ni A se ro won fun yin nitori ki e le dupe (fun Un)
لَنْ يَنَالَ اللَّهَ لُحُومُهَا وَلَا دِمَاؤُهَا وَلَٰكِنْ يَنَالُهُ التَّقْوَىٰ مِنْكُمْ ۚ كَذَٰلِكَ سَخَّرَهَا لَكُمْ لِتُكَبِّرُوا اللَّهَ عَلَىٰ مَا هَدَاكُمْ ۗ وَبَشِّرِ الْمُحْسِنِينَ
Eran (ti e pa) ati eje re ko nii de odo Allahu. Sugbon iberu Allahu lati odo yin l’o maa de odo Re. Bayen ni (Allahu) se ro won fun yin nitori ki e le se igbetobi fun Allahu nipa bi O se fi ona mo yin. Ki o si fun awon oluse-rere ni iro idunnu
إِنَّ اللَّهَ يُدَافِعُ عَنِ الَّذِينَ آمَنُوا ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يُحِبُّ كُلَّ خَوَّانٍ كَفُورٍ
Dajudaju Allahu n ti aburu kuro fun awon t’o gbagbo ni ododo. Dajudaju Allahu ko nifee gbogbo awon onijanba, alaigbagbo
أُذِنَ لِلَّذِينَ يُقَاتَلُونَ بِأَنَّهُمْ ظُلِمُوا ۚ وَإِنَّ اللَّهَ عَلَىٰ نَصْرِهِمْ لَقَدِيرٌ
A yonda (ogun esin jija) fun awon (musulumi) ti (awon keferi) n gbogun ti nitori pe (awon keferi) ti se abosi si won. Dajudaju Allahu ni Alagbara lori aranse won
الَّذِينَ أُخْرِجُوا مِنْ دِيَارِهِمْ بِغَيْرِ حَقٍّ إِلَّا أَنْ يَقُولُوا رَبُّنَا اللَّهُ ۗ وَلَوْلَا دَفْعُ اللَّهِ النَّاسَ بَعْضَهُمْ بِبَعْضٍ لَهُدِّمَتْ صَوَامِعُ وَبِيَعٌ وَصَلَوَاتٌ وَمَسَاجِدُ يُذْكَرُ فِيهَا اسْمُ اللَّهِ كَثِيرًا ۗ وَلَيَنْصُرَنَّ اللَّهُ مَنْ يَنْصُرُهُ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَقَوِيٌّ عَزِيزٌ
(Awon ni) awon ti won le jade kuro ninu ile won ni ona aito afi (nitori pe) won n so pe: “Allahu ni Oluwa wa.” Ti ko ba je pe Allahu n dena (aburu) fun awon eniyan ni, ti O n fi apa kan won dena (aburu) fun apa kan, won iba ti wo ile isin awon fada, soosi, sinagogu ati awon mosalasi ti won ti n daruko Allahu ni opolopo.1 Dajudaju Allahu yoo se aranse fun enikeni t’o n ran (esin ’Islam) Re lowo. Dajudaju Allahu ma ni Alagbara, Olubori

Choose other languages: