Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Hajj Ayahs #29 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ كَفَرُوا وَيَصُدُّونَ عَنْ سَبِيلِ اللَّهِ وَالْمَسْجِدِ الْحَرَامِ الَّذِي جَعَلْنَاهُ لِلنَّاسِ سَوَاءً الْعَاكِفُ فِيهِ وَالْبَادِ ۚ وَمَنْ يُرِدْ فِيهِ بِإِلْحَادٍ بِظُلْمٍ نُذِقْهُ مِنْ عَذَابٍ أَلِيمٍ
Dajudaju awon t’o sai gbagbo, ti won n seri awon eniyan kuro loju ona (esin) Allahu ati Mosalasi Haram, eyi ti A se ni dogbadogba fun awon eniyan, olugbe-inu re ati alejo (fun ijosin sise), enikeni ti o ba ni ero lati se iyipada kan nibe pelu abosi, A maa mu un to iya eleta-elero wo
وَإِذْ بَوَّأْنَا لِإِبْرَاهِيمَ مَكَانَ الْبَيْتِ أَنْ لَا تُشْرِكْ بِي شَيْئًا وَطَهِّرْ بَيْتِيَ لِلطَّائِفِينَ وَالْقَائِمِينَ وَالرُّكَّعِ السُّجُودِ
(E ranti) nigba ti A safi han aye ile naa fun (Anabi) ’Ibrohim (A si pa a lase) pe o o gbodo so kini kan di akegbe fun Mi. Ati pe ki o se ile Mi ni mimo fun awon oluyipo re, olukirun, oludawote-orunkun ati oluforikanle
وَأَذِّنْ فِي النَّاسِ بِالْحَجِّ يَأْتُوكَ رِجَالًا وَعَلَىٰ كُلِّ ضَامِرٍ يَأْتِينَ مِنْ كُلِّ فَجٍّ عَمِيقٍ
Ki o si pe ipe fun awon eniyan fun ise Hajj. Won yoo wa ba o pelu irin ese. Won yo si maa gun awon rakunmi wa lati awon ona jijin
لِيَشْهَدُوا مَنَافِعَ لَهُمْ وَيَذْكُرُوا اسْمَ اللَّهِ فِي أَيَّامٍ مَعْلُومَاتٍ عَلَىٰ مَا رَزَقَهُمْ مِنْ بَهِيمَةِ الْأَنْعَامِ ۖ فَكُلُوا مِنْهَا وَأَطْعِمُوا الْبَائِسَ الْفَقِيرَ
nitori ki won le ri awon anfaani t’o n be fun won ati nitori ki won le seranti oruko Allahu fun awon ojo ti won ti mo lori nnkan ti Allahu pa lese fun won ninu awon eran-osin. Nitori naa, e je ninu re, ki e si fi bo alailera, talika
ثُمَّ لْيَقْضُوا تَفَثَهُمْ وَلْيُوفُوا نُذُورَهُمْ وَلْيَطَّوَّفُوا بِالْبَيْتِ الْعَتِيقِ
Leyin naa, ki won pari ise Hajj won, ki won mu awon eje won se, ki won si yipo Ile Laelae

Choose other languages: