Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Fath Ayahs #29 Translated in Yoruba

إِذْ جَعَلَ الَّذِينَ كَفَرُوا فِي قُلُوبِهِمُ الْحَمِيَّةَ حَمِيَّةَ الْجَاهِلِيَّةِ فَأَنْزَلَ اللَّهُ سَكِينَتَهُ عَلَىٰ رَسُولِهِ وَعَلَى الْمُؤْمِنِينَ وَأَلْزَمَهُمْ كَلِمَةَ التَّقْوَىٰ وَكَانُوا أَحَقَّ بِهَا وَأَهْلَهَا ۚ وَكَانَ اللَّهُ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمًا
(Ranti) nigba ti awon t’o sai gbagbo ko igbonara sinu okan won ni igbonara ti igba aimokan, Allahu si so ifokanbale kale fun Ojise Re ati awon onigbagbo ododo. O si je ki oro iberu (Re) wa pelu won; Won ni eto si i julo, awon ni won si ni in. Allahu si ni Onimo nipa gbogbo nnkan
لَقَدْ صَدَقَ اللَّهُ رَسُولَهُ الرُّؤْيَا بِالْحَقِّ ۖ لَتَدْخُلُنَّ الْمَسْجِدَ الْحَرَامَ إِنْ شَاءَ اللَّهُ آمِنِينَ مُحَلِّقِينَ رُءُوسَكُمْ وَمُقَصِّرِينَ لَا تَخَافُونَ ۖ فَعَلِمَ مَا لَمْ تَعْلَمُوا فَجَعَلَ مِنْ دُونِ ذَٰلِكَ فَتْحًا قَرِيبًا
Dajudaju Allahu ti so ala Ojise Re di ododo pe - ti Allahu ba fe - dajudaju eyin yoo wo inu Mosalasi Haram ni eni ifayabale. E maa fa irun ori yin; e maa ge irun (ori yin mole), e o si nii paya. Nitori naa, (Allahu) mo ohun ti eyin ko mo. Yato si iyen, O tun se isegun t’o sunmo (fun yin)
هُوَ الَّذِي أَرْسَلَ رَسُولَهُ بِالْهُدَىٰ وَدِينِ الْحَقِّ لِيُظْهِرَهُ عَلَى الدِّينِ كُلِّهِ ۚ وَكَفَىٰ بِاللَّهِ شَهِيدًا
(Allahu) Oun ni Eni ti O fi imona ati esin ododo (’Islam) ran Ojise Re nitori ki O le fi bori esin (miiran), gbogbo re patapata. Allahu si to ni Elerii
مُحَمَّدٌ رَسُولُ اللَّهِ ۚ وَالَّذِينَ مَعَهُ أَشِدَّاءُ عَلَى الْكُفَّارِ رُحَمَاءُ بَيْنَهُمْ ۖ تَرَاهُمْ رُكَّعًا سُجَّدًا يَبْتَغُونَ فَضْلًا مِنَ اللَّهِ وَرِضْوَانًا ۖ سِيمَاهُمْ فِي وُجُوهِهِمْ مِنْ أَثَرِ السُّجُودِ ۚ ذَٰلِكَ مَثَلُهُمْ فِي التَّوْرَاةِ ۚ وَمَثَلُهُمْ فِي الْإِنْجِيلِ كَزَرْعٍ أَخْرَجَ شَطْأَهُ فَآزَرَهُ فَاسْتَغْلَظَ فَاسْتَوَىٰ عَلَىٰ سُوقِهِ يُعْجِبُ الزُّرَّاعَ لِيَغِيظَ بِهِمُ الْكُفَّارَ ۗ وَعَدَ اللَّهُ الَّذِينَ آمَنُوا وَعَمِلُوا الصَّالِحَاتِ مِنْهُمْ مَغْفِرَةً وَأَجْرًا عَظِيمًا
Muhammad ni Ojise Allahu. Awon t’o wa pelu re, won le mo awon alaigbagbo, alaaanu si ni won laaarin ara won. O maa ri won ni oludawote-orunkun ati oluforikanle (lori irun), ti won n wa oore ajulo ati iyonu lati odo Allahu. Ami won wa ni oju won nibi oripa iforikanle. Iyen ni apejuwe won ninu Taorah ati apejuwe won ninu ’Injil, gege bi koro eso igi t’o yo ogomo re jade. Leyin naa, o nipon (o lagbara), o si duro gbagidi lori igi re. O si n jo awon agbe loju. (Allahu fi aye gba Anabi ati awon Sohabah re) nitori ki O le fi won se ohun ibinu fun awon alaigbagbo. Allahu sadehun aforijin ati esan nla fun awon t’o gbagbo, ti won si se awon ise rere ninu won

Choose other languages: