Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #286 Translated in Yoruba

وَإِنْ كُنْتُمْ عَلَىٰ سَفَرٍ وَلَمْ تَجِدُوا كَاتِبًا فَرِهَانٌ مَقْبُوضَةٌ ۖ فَإِنْ أَمِنَ بَعْضُكُمْ بَعْضًا فَلْيُؤَدِّ الَّذِي اؤْتُمِنَ أَمَانَتَهُ وَلْيَتَّقِ اللَّهَ رَبَّهُ ۗ وَلَا تَكْتُمُوا الشَّهَادَةَ ۚ وَمَنْ يَكْتُمْهَا فَإِنَّهُ آثِمٌ قَلْبُهُ ۗ وَاللَّهُ بِمَا تَعْمَلُونَ عَلِيمٌ
Ati pe ti e ba wa lori irin-ajo, ti eyin ko si ri akowe, e gba ohun idogo. (Sugbon) ti apa kan yin ba fi okan tan apa kan, ki eni ti won fi okan tan da ohun ti won fi okan tan an le lori pada, ki o si beru Allahu, Oluwa re. E ma se fi eri pamo. Enikeni ti o ba fi pamo, dajudaju okan re ti dese. Allahu si ni Onimo nipa ohun ti e n se
لِلَّهِ مَا فِي السَّمَاوَاتِ وَمَا فِي الْأَرْضِ ۗ وَإِنْ تُبْدُوا مَا فِي أَنْفُسِكُمْ أَوْ تُخْفُوهُ يُحَاسِبْكُمْ بِهِ اللَّهُ ۖ فَيَغْفِرُ لِمَنْ يَشَاءُ وَيُعَذِّبُ مَنْ يَشَاءُ ۗ وَاللَّهُ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ قَدِيرٌ
Ti Allahu ni ohunkohun t’o wa ninu awon sanmo ati ohunkohun t’o wa ninu ile. Ti e ba safi han ohun t’o wa ninu emi yin, tabi e fi pamo, Allahu yo siro re fun yin (ti e ba se e nise). Leyin naa, O maa forijin eni ti O ba fe. O si maa je eni ti O ba fe niya. Allahu si ni Alagbara lori gbogbo nnkan
آمَنَ الرَّسُولُ بِمَا أُنْزِلَ إِلَيْهِ مِنْ رَبِّهِ وَالْمُؤْمِنُونَ ۚ كُلٌّ آمَنَ بِاللَّهِ وَمَلَائِكَتِهِ وَكُتُبِهِ وَرُسُلِهِ لَا نُفَرِّقُ بَيْنَ أَحَدٍ مِنْ رُسُلِهِ ۚ وَقَالُوا سَمِعْنَا وَأَطَعْنَا ۖ غُفْرَانَكَ رَبَّنَا وَإِلَيْكَ الْمَصِيرُ
Ojise naa (sollalahu alayhi wa sallam) gbagbo ninu ohun ti won sokale fun un lati odo Oluwa re. Awon onigbagbo ododo naa (gbagbo ninu re). Eni kookan (won) gbagbo ninu Allahu, awon molaika Re, awon Tira Re ati awon Ojise Re. A ko ya eni kan soto ninu awon Ojise Re. Won si so pe: “A gbo (ase), a si tele (ase). A n toro aforijin Re, Oluwa wa. Odo Re si ni abo eda.”
لَا يُكَلِّفُ اللَّهُ نَفْسًا إِلَّا وُسْعَهَا ۚ لَهَا مَا كَسَبَتْ وَعَلَيْهَا مَا اكْتَسَبَتْ ۗ رَبَّنَا لَا تُؤَاخِذْنَا إِنْ نَسِينَا أَوْ أَخْطَأْنَا ۚ رَبَّنَا وَلَا تَحْمِلْ عَلَيْنَا إِصْرًا كَمَا حَمَلْتَهُ عَلَى الَّذِينَ مِنْ قَبْلِنَا ۚ رَبَّنَا وَلَا تُحَمِّلْنَا مَا لَا طَاقَةَ لَنَا بِهِ ۖ وَاعْفُ عَنَّا وَاغْفِرْ لَنَا وَارْحَمْنَا ۚ أَنْتَ مَوْلَانَا فَانْصُرْنَا عَلَى الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ
Allahu ko labo emi kan lorun afi iwon agbara re. (Esan) ohun ti o se nise (rere) n be fun un. (Iya) ohun ti o se ni’se (ibi) n be fun un pelu. Oluwa wa, ma se mu wa ti a ba gbagbera tabi (ti) a ba sasise. Oluwa wa, ma se di eru t’o wuwo le wa lori, gege bi O se di i ru awon t’o siwaju wa. Oluwa wa, ma se diru wa ohun ti ko si agbara re fun wa. Samoju kuro fun wa, forijin wa, ki O si saanu wa. Iwo ni Alafeyinti wa. Nitori naa, ran wa lowo lori ijo alaigbagbo

Choose other languages: