Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #249 Translated in Yoruba

مَنْ ذَا الَّذِي يُقْرِضُ اللَّهَ قَرْضًا حَسَنًا فَيُضَاعِفَهُ لَهُ أَضْعَافًا كَثِيرَةً ۚ وَاللَّهُ يَقْبِضُ وَيَبْسُطُ وَإِلَيْهِ تُرْجَعُونَ
Ta ni eni ti o maa ya Allahu ni dukia t’o dara, ki Allahu si se adipele (esan) fun un ni adipele pupo? Allahu n ka oro nile, O si n te e sile. Odo Re si ni won yoo da yin pada si
أَلَمْ تَرَ إِلَى الْمَلَإِ مِنْ بَنِي إِسْرَائِيلَ مِنْ بَعْدِ مُوسَىٰ إِذْ قَالُوا لِنَبِيٍّ لَهُمُ ابْعَثْ لَنَا مَلِكًا نُقَاتِلْ فِي سَبِيلِ اللَّهِ ۖ قَالَ هَلْ عَسَيْتُمْ إِنْ كُتِبَ عَلَيْكُمُ الْقِتَالُ أَلَّا تُقَاتِلُوا ۖ قَالُوا وَمَا لَنَا أَلَّا نُقَاتِلَ فِي سَبِيلِ اللَّهِ وَقَدْ أُخْرِجْنَا مِنْ دِيَارِنَا وَأَبْنَائِنَا ۖ فَلَمَّا كُتِبَ عَلَيْهِمُ الْقِتَالُ تَوَلَّوْا إِلَّا قَلِيلًا مِنْهُمْ ۗ وَاللَّهُ عَلِيمٌ بِالظَّالِمِينَ
Se o o ri awon asiwaju ninu awon omo ’Isro’il, leyin (igba Anabi) Musa? Nigba ti won wi fun Anabi tiwon pe: “Yan oba kan fun wa, ki a lo jagun fun aabo esin Allahu.” O so pe: “Sebi o se e se pe ti Won ba se ogun jija ni oran-anyan le yin lori tan e o kuku nii jagun?” Won wi pe: "Ki ni o maa di wa lowo lati jagun fun aabo esin Allahu? Won kuku ti le awa ati awon omo wa jade kuro ninu ile wa!" Amo nigba ti A se ogun esin ni oran-anyan le won lori tan, won peyin da afi die ninu won. Allahu si ni Onimo nipa awon alabosi
وَقَالَ لَهُمْ نَبِيُّهُمْ إِنَّ اللَّهَ قَدْ بَعَثَ لَكُمْ طَالُوتَ مَلِكًا ۚ قَالُوا أَنَّىٰ يَكُونُ لَهُ الْمُلْكُ عَلَيْنَا وَنَحْنُ أَحَقُّ بِالْمُلْكِ مِنْهُ وَلَمْ يُؤْتَ سَعَةً مِنَ الْمَالِ ۚ قَالَ إِنَّ اللَّهَ اصْطَفَاهُ عَلَيْكُمْ وَزَادَهُ بَسْطَةً فِي الْعِلْمِ وَالْجِسْمِ ۖ وَاللَّهُ يُؤْتِي مُلْكَهُ مَنْ يَشَاءُ ۚ وَاللَّهُ وَاسِعٌ عَلِيمٌ
Anabi won so fun won pe: “Dajudaju Allahu ti gbe Tolut dide fun yin ni oba.” Won wi pe: “Bawo ni o se le je oba le wa lori nigba ti o je pe awa ni eto si ipo oba ju u lo? Ko si ni owo pupo lowo?” O so pe: "Dajudaju Allahu sa a lesa le yin lori. O si fun un ni alekun pupo ninu imo ati okun ara. Allahu n fun eni ti O ba fe ni ijoba Re. Allahu ni Olugbaaye, Onimo
وَقَالَ لَهُمْ نَبِيُّهُمْ إِنَّ آيَةَ مُلْكِهِ أَنْ يَأْتِيَكُمُ التَّابُوتُ فِيهِ سَكِينَةٌ مِنْ رَبِّكُمْ وَبَقِيَّةٌ مِمَّا تَرَكَ آلُ مُوسَىٰ وَآلُ هَارُونَ تَحْمِلُهُ الْمَلَائِكَةُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Anabi won tun so fun won pe: "Dajudaju ami ijoba re ni pe, apoti yoo wa ba yin. Nnkan ifayabale lati odo Oluwa yin ati ohun t’o seku ninu ohun ti awon eniyan (Anabi) Musa ati eniyan (Anabi) Harun fi sile n be ninu apoti naa. Awon molaika maa ru u wa (ba yin). Dajudaju ami wa ninu iyen fun yin, ti e ba je onigbagbo ododo
فَلَمَّا فَصَلَ طَالُوتُ بِالْجُنُودِ قَالَ إِنَّ اللَّهَ مُبْتَلِيكُمْ بِنَهَرٍ فَمَنْ شَرِبَ مِنْهُ فَلَيْسَ مِنِّي وَمَنْ لَمْ يَطْعَمْهُ فَإِنَّهُ مِنِّي إِلَّا مَنِ اغْتَرَفَ غُرْفَةً بِيَدِهِ ۚ فَشَرِبُوا مِنْهُ إِلَّا قَلِيلًا مِنْهُمْ ۚ فَلَمَّا جَاوَزَهُ هُوَ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ قَالُوا لَا طَاقَةَ لَنَا الْيَوْمَ بِجَالُوتَ وَجُنُودِهِ ۚ قَالَ الَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُمْ مُلَاقُو اللَّهِ كَمْ مِنْ فِئَةٍ قَلِيلَةٍ غَلَبَتْ فِئَةً كَثِيرَةً بِإِذْنِ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ مَعَ الصَّابِرِينَ
Nigba ti Tolut jade pelu awon omo ogun, o so pe: “Dajudaju Allahu maa fi odo kan dan yin wo. Nitori naa, enikeni ti o ba mu ninu re, ki i se eni mi. Eni ti ko ba to o wo dajudaju oun ni eni mi, ayafi eni ti o ba bu iwon ekunwo re kan mu.” (Sugbon) won mu ninu re afi die ninu won. Nigba ti oun ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re soda odo naa, won so pe: “Ko si agbara kan fun wa lonii ti a le fi k’oju Jalut ati awon omo ogun re.” Awon t’o mo pe dajudaju awon maa pade Allahu, won so pe: "Meloo meloo ninu awon ijo (ogun) kekere t’o ti segun ijo (ogun) pupo pelu iyonda Allahu. Allahu n be pelu awon onisuuru

Choose other languages: