Surah Al-Baqara Ayahs #252 Translated in Yoruba
وَقَالَ لَهُمْ نَبِيُّهُمْ إِنَّ آيَةَ مُلْكِهِ أَنْ يَأْتِيَكُمُ التَّابُوتُ فِيهِ سَكِينَةٌ مِنْ رَبِّكُمْ وَبَقِيَّةٌ مِمَّا تَرَكَ آلُ مُوسَىٰ وَآلُ هَارُونَ تَحْمِلُهُ الْمَلَائِكَةُ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
Anabi won tun so fun won pe: "Dajudaju ami ijoba re ni pe, apoti yoo wa ba yin. Nnkan ifayabale lati odo Oluwa yin ati ohun t’o seku ninu ohun ti awon eniyan (Anabi) Musa ati eniyan (Anabi) Harun fi sile n be ninu apoti naa. Awon molaika maa ru u wa (ba yin). Dajudaju ami wa ninu iyen fun yin, ti e ba je onigbagbo ododo
فَلَمَّا فَصَلَ طَالُوتُ بِالْجُنُودِ قَالَ إِنَّ اللَّهَ مُبْتَلِيكُمْ بِنَهَرٍ فَمَنْ شَرِبَ مِنْهُ فَلَيْسَ مِنِّي وَمَنْ لَمْ يَطْعَمْهُ فَإِنَّهُ مِنِّي إِلَّا مَنِ اغْتَرَفَ غُرْفَةً بِيَدِهِ ۚ فَشَرِبُوا مِنْهُ إِلَّا قَلِيلًا مِنْهُمْ ۚ فَلَمَّا جَاوَزَهُ هُوَ وَالَّذِينَ آمَنُوا مَعَهُ قَالُوا لَا طَاقَةَ لَنَا الْيَوْمَ بِجَالُوتَ وَجُنُودِهِ ۚ قَالَ الَّذِينَ يَظُنُّونَ أَنَّهُمْ مُلَاقُو اللَّهِ كَمْ مِنْ فِئَةٍ قَلِيلَةٍ غَلَبَتْ فِئَةً كَثِيرَةً بِإِذْنِ اللَّهِ ۗ وَاللَّهُ مَعَ الصَّابِرِينَ
Nigba ti Tolut jade pelu awon omo ogun, o so pe: “Dajudaju Allahu maa fi odo kan dan yin wo. Nitori naa, enikeni ti o ba mu ninu re, ki i se eni mi. Eni ti ko ba to o wo dajudaju oun ni eni mi, ayafi eni ti o ba bu iwon ekunwo re kan mu.” (Sugbon) won mu ninu re afi die ninu won. Nigba ti oun ati awon t’o gbagbo ni ododo pelu re soda odo naa, won so pe: “Ko si agbara kan fun wa lonii ti a le fi k’oju Jalut ati awon omo ogun re.” Awon t’o mo pe dajudaju awon maa pade Allahu, won so pe: "Meloo meloo ninu awon ijo (ogun) kekere t’o ti segun ijo (ogun) pupo pelu iyonda Allahu. Allahu n be pelu awon onisuuru
وَلَمَّا بَرَزُوا لِجَالُوتَ وَجُنُودِهِ قَالُوا رَبَّنَا أَفْرِغْ عَلَيْنَا صَبْرًا وَثَبِّتْ أَقْدَامَنَا وَانْصُرْنَا عَلَى الْقَوْمِ الْكَافِرِينَ
Nigba ti won jade si Jalut ati awon omo ogun re, won so pe: "Oluwa wa, fun wa ni omi suuru mu, fi ese wa rinle sinsin, ki O si ran wa lowo lori ijo alaigbagbo
فَهَزَمُوهُمْ بِإِذْنِ اللَّهِ وَقَتَلَ دَاوُودُ جَالُوتَ وَآتَاهُ اللَّهُ الْمُلْكَ وَالْحِكْمَةَ وَعَلَّمَهُ مِمَّا يَشَاءُ ۗ وَلَوْلَا دَفْعُ اللَّهِ النَّاسَ بَعْضَهُمْ بِبَعْضٍ لَفَسَدَتِ الْأَرْضُ وَلَٰكِنَّ اللَّهَ ذُو فَضْلٍ عَلَى الْعَالَمِينَ
Won si segun won pelu iyonda Allahu. Dawud si pa Jalut. Allahu si fun un ni ijoba ati ogbon. O tun fi imo mo on ninu ohun ti O ba fe. Ti ko ba je pe Allahu n dena (aburu) fun awon eniyan ni, ti O n fi apa kan won dena (aburu) fun apa kan, ori ile iba ti baje. Sugbon Allahu ni Oloore ajulo lori gbogbo eda
تِلْكَ آيَاتُ اللَّهِ نَتْلُوهَا عَلَيْكَ بِالْحَقِّ ۚ وَإِنَّكَ لَمِنَ الْمُرْسَلِينَ
Iwonyi ni awon ayah Allahu, ti A n ke e fun o pelu ododo. Ati pe dajudaju iwo wa lara awon Ojise
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
