Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #223 Translated in Yoruba

يَسْأَلُونَكَ عَنِ الْخَمْرِ وَالْمَيْسِرِ ۖ قُلْ فِيهِمَا إِثْمٌ كَبِيرٌ وَمَنَافِعُ لِلنَّاسِ وَإِثْمُهُمَا أَكْبَرُ مِنْ نَفْعِهِمَا ۗ وَيَسْأَلُونَكَ مَاذَا يُنْفِقُونَ قُلِ الْعَفْوَ ۗ كَذَٰلِكَ يُبَيِّنُ اللَّهُ لَكُمُ الْآيَاتِ لَعَلَّكُمْ تَتَفَكَّرُونَ
Won n bi o leere nipa oti ati tete. So pe: "Ese nla ati awon anfaani kan wa ninu mejeeji fun awon eniyan. Ese mejeeji si tobi ju anfaani won lo." Won tun n bi o leere pe ki ni awon yo maa na ni saraa. So pe: “Ohun ti o ba seku leyin ti e ba ti gbo bukata inu ile tan (ni ki e fi se saraa).” Bayen ni Allahu se n s’alaye awon ayah fun yin nitori ki e le ronu jinle
فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ ۗ وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْيَتَامَىٰ ۖ قُلْ إِصْلَاحٌ لَهُمْ خَيْرٌ ۖ وَإِنْ تُخَالِطُوهُمْ فَإِخْوَانُكُمْ ۚ وَاللَّهُ يَعْلَمُ الْمُفْسِدَ مِنَ الْمُصْلِحِ ۚ وَلَوْ شَاءَ اللَّهُ لَأَعْنَتَكُمْ ۚ إِنَّ اللَّهَ عَزِيزٌ حَكِيمٌ
nipa aye ati orun. Won n bi o leere nipa awon omo orukan. So pe: "Sise atunse dukia won (lai nii da a po mo dukia yin) l’o dara julo. Ti e ba si da a po mo dukia yin, omo iya yin (ninu esin) kuku ni won. Allahu si mo obileje yato si alatun-unse. Ati pe ti o ba je pe Allahu ba fe (ki e ya dukia won si oto nikan ni) iba ko inira ba yin. Dajudaju Allahu ni Alagbara, Ologbon
وَلَا تَنْكِحُوا الْمُشْرِكَاتِ حَتَّىٰ يُؤْمِنَّ ۚ وَلَأَمَةٌ مُؤْمِنَةٌ خَيْرٌ مِنْ مُشْرِكَةٍ وَلَوْ أَعْجَبَتْكُمْ ۗ وَلَا تُنْكِحُوا الْمُشْرِكِينَ حَتَّىٰ يُؤْمِنُوا ۚ وَلَعَبْدٌ مُؤْمِنٌ خَيْرٌ مِنْ مُشْرِكٍ وَلَوْ أَعْجَبَكُمْ ۗ أُولَٰئِكَ يَدْعُونَ إِلَى النَّارِ ۖ وَاللَّهُ يَدْعُو إِلَى الْجَنَّةِ وَالْمَغْفِرَةِ بِإِذْنِهِ ۖ وَيُبَيِّنُ آيَاتِهِ لِلنَّاسِ لَعَلَّهُمْ يَتَذَكَّرُونَ
E ma fi awon aborisa lobinrin saya titi won yo fi gbagbo ni ododo. Dajudaju erubinrin onigbagbo ododo loore ju aborisa lobinrin, koda ki aborisa lobinrin jo yin loju. E ma si fi onigbagbo ododo lobinrin fun awon aborisa lokunrin titi won yo fi gbagbo ni ododo. Erukunrin onigbagbo ododo loore ju aborisa lokunrin, koda ki aborisa lokunrin jo yin loju. Awon (aborisa) wonyen n pepe sinu Ina. Allahu si n pepe sinu Ogba Idera ati aforijin pelu iyonda Re. O si n salaye awon ayah Re fun awon eniyan nitori ki won le lo iranti
وَيَسْأَلُونَكَ عَنِ الْمَحِيضِ ۖ قُلْ هُوَ أَذًى فَاعْتَزِلُوا النِّسَاءَ فِي الْمَحِيضِ ۖ وَلَا تَقْرَبُوهُنَّ حَتَّىٰ يَطْهُرْنَ ۖ فَإِذَا تَطَهَّرْنَ فَأْتُوهُنَّ مِنْ حَيْثُ أَمَرَكُمُ اللَّهُ ۚ إِنَّ اللَّهَ يُحِبُّ التَّوَّابِينَ وَيُحِبُّ الْمُتَطَهِّرِينَ
Won si n bi o leere nipa nnkan osu (obinrin). So pe: “Inira ni (sisunmo won lasiko naa). Nitori naa, e yera fun awon obinrin l’asiko nnkan osu. E ma se sunmo won (fun oorun ife) titi won yo fi se imora. Ti won ba si ti se imora, e sunmo won ni aye ti Allahu pa lase fun yin. Dajudaju Allahu nifee awon oluronu-piwada. O si nifee awon olumora
نِسَاؤُكُمْ حَرْثٌ لَكُمْ فَأْتُوا حَرْثَكُمْ أَنَّىٰ شِئْتُمْ ۖ وَقَدِّمُوا لِأَنْفُسِكُمْ ۚ وَاتَّقُوا اللَّهَ وَاعْلَمُوا أَنَّكُمْ مُلَاقُوهُ ۗ وَبَشِّرِ الْمُؤْمِنِينَ
Awon obinrin yin, oko ni won fun yin. E lo s’inu oko yin bi e ba se fe, ki e si ti (ise rere) siwaju fun emi ara yin. E beru Allahu. Ki e mo pe dajudaju e maa pade Re. Ki o si fun awon onigbagbo ododo ni iro idunnu

Choose other languages: