Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Baqara Ayahs #160 Translated in Yoruba

الَّذِينَ إِذَا أَصَابَتْهُمْ مُصِيبَةٌ قَالُوا إِنَّا لِلَّهِ وَإِنَّا إِلَيْهِ رَاجِعُونَ
Awon ti (o je pe) nigba ti adanwo kan ba kan won, won a so pe: “Dajudaju Allahu l’O ni awa; dajudaju odo Re si ni awa yoo pada si.”
أُولَٰئِكَ عَلَيْهِمْ صَلَوَاتٌ مِنْ رَبِّهِمْ وَرَحْمَةٌ ۖ وَأُولَٰئِكَ هُمُ الْمُهْتَدُونَ
Awon wonyen ni aforijin ati ike yo maa be fun lati odo Oluwa won. Awon wonyen, awon si ni olumona
إِنَّ الصَّفَا وَالْمَرْوَةَ مِنْ شَعَائِرِ اللَّهِ ۖ فَمَنْ حَجَّ الْبَيْتَ أَوِ اعْتَمَرَ فَلَا جُنَاحَ عَلَيْهِ أَنْ يَطَّوَّفَ بِهِمَا ۚ وَمَنْ تَطَوَّعَ خَيْرًا فَإِنَّ اللَّهَ شَاكِرٌ عَلِيمٌ
Dajudaju (apata) Sofa ati (apata) Morwah wa ninu awon arisami fun esin Allahu. Nitori naa, enikeni ti o ba se ise Hajj si Ile naa tabi o se ise ‘Umrah, ko si ese fun un lati rin yika (laaarin apata) mejeeji. Enikeni ti o ba si finnu-findo se ise asegbore, dajudaju Allahu ni Amoore, Onimo
إِنَّ الَّذِينَ يَكْتُمُونَ مَا أَنْزَلْنَا مِنَ الْبَيِّنَاتِ وَالْهُدَىٰ مِنْ بَعْدِ مَا بَيَّنَّاهُ لِلنَّاسِ فِي الْكِتَابِ ۙ أُولَٰئِكَ يَلْعَنُهُمُ اللَّهُ وَيَلْعَنُهُمُ اللَّاعِنُونَ
Dajudaju awon t’o n daso bo ohun ti A sokale ninu awon eri t’o yanju ati imona, leyin ti A ti se alaye re fun awon eniyan sinu Tira, awon wonyen ni Allahu n sebi le. Awon olusebi si n sebi le won
إِلَّا الَّذِينَ تَابُوا وَأَصْلَحُوا وَبَيَّنُوا فَأُولَٰئِكَ أَتُوبُ عَلَيْهِمْ ۚ وَأَنَا التَّوَّابُ الرَّحِيمُ
Ayafi awon t’o ronu piwada, ti won se atunse, ti won si safi han ododo, nitori naa awon wonyen ni Mo maa gba ironupiwada won. Emi si ni Olugba-ironupiwada, Asake-orun

Choose other languages: