Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #41 Translated in Yoruba

فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا أَوْ كَذَّبَ بِآيَاتِهِ ۚ أُولَٰئِكَ يَنَالُهُمْ نَصِيبُهُمْ مِنَ الْكِتَابِ ۖ حَتَّىٰ إِذَا جَاءَتْهُمْ رُسُلُنَا يَتَوَفَّوْنَهُمْ قَالُوا أَيْنَ مَا كُنْتُمْ تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ ۖ قَالُوا ضَلُّوا عَنَّا وَشَهِدُوا عَلَىٰ أَنْفُسِهِمْ أَنَّهُمْ كَانُوا كَافِرِينَ
Nitori naa, ta l’o sabosi ju eni t’o da adapa iro mo Allahu tabi t’o pe awon ayah Re niro? Ipin awon wonyen ninu kadara yoo maa te won lowo titi di igba ti awon Ojise Wa yoo wa ba won, ti won yoo gba emi won. Won yo si so pe: "Nibo ni awon nnkan ti eyin n pe leyin Allahu wa?" Won yoo wi pe: “Won ti di ofo mo wa lowo." Won si jerii lera won lori pe dajudaju awon je alaigbagbo.”
قَالَ ادْخُلُوا فِي أُمَمٍ قَدْ خَلَتْ مِنْ قَبْلِكُمْ مِنَ الْجِنِّ وَالْإِنْسِ فِي النَّارِ ۖ كُلَّمَا دَخَلَتْ أُمَّةٌ لَعَنَتْ أُخْتَهَا ۖ حَتَّىٰ إِذَا ادَّارَكُوا فِيهَا جَمِيعًا قَالَتْ أُخْرَاهُمْ لِأُولَاهُمْ رَبَّنَا هَٰؤُلَاءِ أَضَلُّونَا فَآتِهِمْ عَذَابًا ضِعْفًا مِنَ النَّارِ ۖ قَالَ لِكُلٍّ ضِعْفٌ وَلَٰكِنْ لَا تَعْلَمُونَ
(Allahu) so pe: "E wole ti awon ijo t’o ti re koja lo siwaju yin ninu awon alujannu ati eniyan (ti won ti wa) ninu Ina." Igbakigba ti ijo kan ba wo (inu Ina), won yoo maa sebi fun awon ijo re (t’o ti wa nibe siwaju won), titi di igba ti gbogbo won yoo fi pade ara won ninu Ina. (Igba yii ni) awon eni ikeyin won yoo wi fun awon eni isaaju won pe: "Oluwa wa, awon wonyi ni won si wa lona. Nitori naa, fun won ni ilopo iya meji ninu Ina." (Allahu) so pe: "Ikookan (yin) l’o ni ilopo iya, sugbon eyin ko mo
وَقَالَتْ أُولَاهُمْ لِأُخْرَاهُمْ فَمَا كَانَ لَكُمْ عَلَيْنَا مِنْ فَضْلٍ فَذُوقُوا الْعَذَابَ بِمَا كُنْتُمْ تَكْسِبُونَ
Awon eni akoko won yo si wi fun awon eni ikeyin won pe: "Ko si ajulo kan fun yin lori wa. Nitori naa, e to Iya wo nitori ohun ti e n se nise
إِنَّ الَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَاسْتَكْبَرُوا عَنْهَا لَا تُفَتَّحُ لَهُمْ أَبْوَابُ السَّمَاءِ وَلَا يَدْخُلُونَ الْجَنَّةَ حَتَّىٰ يَلِجَ الْجَمَلُ فِي سَمِّ الْخِيَاطِ ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الْمُجْرِمِينَ
Dajudaju awon t’o pe awon ayah Wa niro, ti won si segberaga si i, Won ko nii si awon ilekun sanmo fun won. Won ko si nii wo inu Ogba Idera titi rakunmi yoo wo inu iho abere. Bayen ni A se n san awon elese ni esan
لَهُمْ مِنْ جَهَنَّمَ مِهَادٌ وَمِنْ فَوْقِهِمْ غَوَاشٍ ۚ وَكَذَٰلِكَ نَجْزِي الظَّالِمِينَ
Ite wa fun won ninu ina Jahanamo. Orule si wa fun won ni oke won. Bayen ni A se n san awon alabosi ni esan

Choose other languages: