Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #148 Translated in Yoruba

قَالَ يَا مُوسَىٰ إِنِّي اصْطَفَيْتُكَ عَلَى النَّاسِ بِرِسَالَاتِي وَبِكَلَامِي فَخُذْ مَا آتَيْتُكَ وَكُنْ مِنَ الشَّاكِرِينَ
(Allahu) so pe: "Musa, dajudaju Emi sa o lesa lori awon eniyan pelu awon ise Mi ati oro Mi. Nitori naa, gba ohun ti Mo fun o mu. Ki o si wa ninu awon oludupe
وَكَتَبْنَا لَهُ فِي الْأَلْوَاحِ مِنْ كُلِّ شَيْءٍ مَوْعِظَةً وَتَفْصِيلًا لِكُلِّ شَيْءٍ فَخُذْهَا بِقُوَّةٍ وَأْمُرْ قَوْمَكَ يَأْخُذُوا بِأَحْسَنِهَا ۚ سَأُرِيكُمْ دَارَ الْفَاسِقِينَ
A si ko gbogbo nnkan fun un sinu awon walaa. (O je) waasi ati alaye oro fun gbogbo nnkan. Nitori naa, samulo re daradara. Ki o si pa ijo re lase pe ki won samulo nnkan daadaa t’o n be ninu re. Emi yoo fi ile awon arufin han yin
سَأَصْرِفُ عَنْ آيَاتِيَ الَّذِينَ يَتَكَبَّرُونَ فِي الْأَرْضِ بِغَيْرِ الْحَقِّ وَإِنْ يَرَوْا كُلَّ آيَةٍ لَا يُؤْمِنُوا بِهَا وَإِنْ يَرَوْا سَبِيلَ الرُّشْدِ لَا يَتَّخِذُوهُ سَبِيلًا وَإِنْ يَرَوْا سَبِيلَ الْغَيِّ يَتَّخِذُوهُ سَبِيلًا ۚ ذَٰلِكَ بِأَنَّهُمْ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَكَانُوا عَنْهَا غَافِلِينَ
Emi yoo seri awon t’o n segberaga lori ile lai letoo kuro nibi awon ami Mi. Ti won ba si ri gbogbo ami, won ko nii gba a gbo. Ti won ba ri ona imona, won ko nii mu un ni ona. Ti won ba si ri ona isina, won yoo mu un ni ona. Iyen nitori pe won pe awon ami Wa niro; won si je afonufora nipa re
وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا وَلِقَاءِ الْآخِرَةِ حَبِطَتْ أَعْمَالُهُمْ ۚ هَلْ يُجْزَوْنَ إِلَّا مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Awon t’o si pe awon ayah Wa ati ipade Ojo Ikeyin ni iro, awon ise won ti baje. Se A oo san won ni esan kan ni bi ko se ohun ti won n se nise
وَاتَّخَذَ قَوْمُ مُوسَىٰ مِنْ بَعْدِهِ مِنْ حُلِيِّهِمْ عِجْلًا جَسَدًا لَهُ خُوَارٌ ۚ أَلَمْ يَرَوْا أَنَّهُ لَا يُكَلِّمُهُمْ وَلَا يَهْدِيهِمْ سَبِيلًا ۘ اتَّخَذُوهُ وَكَانُوا ظَالِمِينَ
Awon eniyan (Anabi) Musa, leyin re (nigba ti o fi lo ba Allahu soro), won mu ninu oso won (lati fi se) ere omo maalu oborogidi, o si n dun (bii maalu). Se won ko ri i pe dajudaju ko le ba won soro ni, ko si le fi ona mo won? Won si so o di akunlebo. Won si je alabosi

Choose other languages: