Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Araf Ayahs #129 Translated in Yoruba

قَالُوا إِنَّا إِلَىٰ رَبِّنَا مُنْقَلِبُونَ
Won so pe: "Dajudaju odo Oluwa wa si ni a maa fabo si
وَمَا تَنْقِمُ مِنَّا إِلَّا أَنْ آمَنَّا بِآيَاتِ رَبِّنَا لَمَّا جَاءَتْنَا ۚ رَبَّنَا أَفْرِغْ عَلَيْنَا صَبْرًا وَتَوَفَّنَا مُسْلِمِينَ
Ati pe o o tako kini kan lara wa lati fiya je wa bi ko se nitori pe a gba awon ami Oluwa wa gbo nigba ti o de ba wa. Oluwa wa, fun wa ni omi suuru mu. Ki O si pa wa sipo musulumi
وَقَالَ الْمَلَأُ مِنْ قَوْمِ فِرْعَوْنَ أَتَذَرُ مُوسَىٰ وَقَوْمَهُ لِيُفْسِدُوا فِي الْأَرْضِ وَيَذَرَكَ وَآلِهَتَكَ ۚ قَالَ سَنُقَتِّلُ أَبْنَاءَهُمْ وَنَسْتَحْيِي نِسَاءَهُمْ وَإِنَّا فَوْقَهُمْ قَاهِرُونَ
Awon ijoye ninu ijo Fir‘aon wi pe: "Se iwo yoo fi Musa ati awon eniyan re sile nitori ki won le sebaje lori ile ati nitori ki o le pa iwo ati awon orisa re ti?" (Fir‘aon) wi pe: "A oo maa pa awon omokunrin won ni. A o si maa da awon omobinrin won si. Dajudaju awa ni alagbara lori won
قَالَ مُوسَىٰ لِقَوْمِهِ اسْتَعِينُوا بِاللَّهِ وَاصْبِرُوا ۖ إِنَّ الْأَرْضَ لِلَّهِ يُورِثُهَا مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۖ وَالْعَاقِبَةُ لِلْمُتَّقِينَ
(Anabi) Musa so fun ijo re pe: "E fi Allahu wa iranlowo, ki e si se suuru. Dajudaju ti Allahu ni ile. O si n jogun re fun eni t’O ba fe ninu awon erusin Re. Igbeyin (rere) si wa fun awon oluberu (Allahu)
قَالُوا أُوذِينَا مِنْ قَبْلِ أَنْ تَأْتِيَنَا وَمِنْ بَعْدِ مَا جِئْتَنَا ۚ قَالَ عَسَىٰ رَبُّكُمْ أَنْ يُهْلِكَ عَدُوَّكُمْ وَيَسْتَخْلِفَكُمْ فِي الْأَرْضِ فَيَنْظُرَ كَيْفَ تَعْمَلُونَ
Won so pe: “Won ni wa larasiwaju ki o to wa ba wa ati leyin ti o de ba wa.” (Anabi Musa) so pe: “O le je pe Allahu yoo pa awon ota yin run. O si maa fi yin ropo (won) lori ile. Nigba naa, (Allahu) yo si wo bi eyin naa yoo se maa se.”

Choose other languages: