Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #92 Translated in Yoruba

ذَٰلِكَ هُدَى اللَّهِ يَهْدِي بِهِ مَنْ يَشَاءُ مِنْ عِبَادِهِ ۚ وَلَوْ أَشْرَكُوا لَحَبِطَ عَنْهُمْ مَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Iyen ni imona Allahu. O si n fi to eni ti O ba fe si ona ninu awon eru Re. Ti won ba fi le sebo ni, dajudaju ohun ti won n se nise (rere) iba baje mo won lowo
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ آتَيْنَاهُمُ الْكِتَابَ وَالْحُكْمَ وَالنُّبُوَّةَ ۚ فَإِنْ يَكْفُرْ بِهَا هَٰؤُلَاءِ فَقَدْ وَكَّلْنَا بِهَا قَوْمًا لَيْسُوا بِهَا بِكَافِرِينَ
Awon wonyen ni awon ti A fun ni Tira, ijinle oye (iyen, sunnah) ati (ipo) Anabi. Nitori naa, ti awon wonyi ba sai gbagbo ninu re, dajudaju A ti gbe e le awon eniyan kan lowo, ti won ko nii sai gbagbo ninu re
أُولَٰئِكَ الَّذِينَ هَدَى اللَّهُ ۖ فَبِهُدَاهُمُ اقْتَدِهْ ۗ قُلْ لَا أَسْأَلُكُمْ عَلَيْهِ أَجْرًا ۖ إِنْ هُوَ إِلَّا ذِكْرَىٰ لِلْعَالَمِينَ
Awon wonyen ni awon ti Allahu to si ona. Nitori naa, ona won ni ki o tele. So pe: “Emi ko bi yin ni owo-oya kan lori re. Ki si ni al-Ƙur’an bi ko se iranti fun gbogbo eda.”
وَمَا قَدَرُوا اللَّهَ حَقَّ قَدْرِهِ إِذْ قَالُوا مَا أَنْزَلَ اللَّهُ عَلَىٰ بَشَرٍ مِنْ شَيْءٍ ۗ قُلْ مَنْ أَنْزَلَ الْكِتَابَ الَّذِي جَاءَ بِهِ مُوسَىٰ نُورًا وَهُدًى لِلنَّاسِ ۖ تَجْعَلُونَهُ قَرَاطِيسَ تُبْدُونَهَا وَتُخْفُونَ كَثِيرًا ۖ وَعُلِّمْتُمْ مَا لَمْ تَعْلَمُوا أَنْتُمْ وَلَا آبَاؤُكُمْ ۖ قُلِ اللَّهُ ۖ ثُمَّ ذَرْهُمْ فِي خَوْضِهِمْ يَلْعَبُونَ
Won ko fun Allahu ni iyi ti o to si I, nigba ti won wi pe: “Allahu ko so nnkan kan kale fun abara kan.” So pe: "Ta ni O so tira ti (Anabi) Musa mu wa kale, (eyi t’o je) imole ati imona fun awon eniyan, eyi ti e sakosile re sinu iwe ajako, ti e n se afihan re, ti e si n fi opolopo re pamo, A si fi ohun ti e o mo mo yin, eyin ati awon baba yin?" So pe: "Allahu ni." Leyin naa, fi won sile sinu isokuso won, ki won maa sere
وَهَٰذَا كِتَابٌ أَنْزَلْنَاهُ مُبَارَكٌ مُصَدِّقُ الَّذِي بَيْنَ يَدَيْهِ وَلِتُنْذِرَ أُمَّ الْقُرَىٰ وَمَنْ حَوْلَهَا ۚ وَالَّذِينَ يُؤْمِنُونَ بِالْآخِرَةِ يُؤْمِنُونَ بِهِ ۖ وَهُمْ عَلَىٰ صَلَاتِهِمْ يُحَافِظُونَ
Eyi (al-Ƙur’an) tun ni Tira ibukun ti A sokale; o n jerii si eyi t’o je ododo ninu eyi t’o siwaju re ati pe nitori ki o le se ikilo fun ’Ummul-Ƙuro (iyen, ara ilu Mokkah) ati enikeni ti o ba wa ni ayika re (iyen, ara ilu yooku). Awon t’o gbagbo ninu Ojo Ikeyin, won gbagbo ninu re. Awon si ni won n so irun won

Choose other languages: