Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #42 Translated in Yoruba

وَمَا مِنْ دَابَّةٍ فِي الْأَرْضِ وَلَا طَائِرٍ يَطِيرُ بِجَنَاحَيْهِ إِلَّا أُمَمٌ أَمْثَالُكُمْ ۚ مَا فَرَّطْنَا فِي الْكِتَابِ مِنْ شَيْءٍ ۚ ثُمَّ إِلَىٰ رَبِّهِمْ يُحْشَرُونَ
Ko si ohun abemi kan (t’o n rin) lori ile, tabi eye kan t’o n fo pelu apa re mejeeji bi ko se awon eda kan (bi) iru yin. A ko fi kini kan sile (lai sakosile re) sinu Tira (iyen, ummul-kitab). Leyin naa, odo Oluwa won ni won yoo ko won jo si
وَالَّذِينَ كَذَّبُوا بِآيَاتِنَا صُمٌّ وَبُكْمٌ فِي الظُّلُمَاتِ ۗ مَنْ يَشَإِ اللَّهُ يُضْلِلْهُ وَمَنْ يَشَأْ يَجْعَلْهُ عَلَىٰ صِرَاطٍ مُسْتَقِيمٍ
Awon t’o pe awon ayah Wa niro, aditi ati ayaya t’o wa ninu awon okunkun ni won. Enikeni ti Allahu ba fe, O maa si i lona. Enikeni ti O ba si fe, O maa fi soju ona taara (’Islam)
قُلْ أَرَأَيْتَكُمْ إِنْ أَتَاكُمْ عَذَابُ اللَّهِ أَوْ أَتَتْكُمُ السَّاعَةُ أَغَيْرَ اللَّهِ تَدْعُونَ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
So pe: "E so fun mi, ti iya Allahu ba de ba yin tabi ti Akoko naa ba de ba yin, se nnkan miiran leyin Allahu ni eyin maa pe, ti e ba je olododo
بَلْ إِيَّاهُ تَدْعُونَ فَيَكْشِفُ مَا تَدْعُونَ إِلَيْهِ إِنْ شَاءَ وَتَنْسَوْنَ مَا تُشْرِكُونَ
Rara, Oun (nikan) l’e n pe. O si maa mu (inira) ti e n pe E si kuro (fun yin), ti O ba fe. Eyin yo si gbagbe ohun ti e n fi sebo si I
وَلَقَدْ أَرْسَلْنَا إِلَىٰ أُمَمٍ مِنْ قَبْلِكَ فَأَخَذْنَاهُمْ بِالْبَأْسَاءِ وَالضَّرَّاءِ لَعَلَّهُمْ يَتَضَرَّعُونَ
Dajudaju A ti ranse si awon ijo kan siwaju re. A si fi iponju ati ailera gba won mu nitori ki won le rawo rase (si Allahu)

Choose other languages: