Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #142 Translated in Yoruba

وَقَالُوا هَٰذِهِ أَنْعَامٌ وَحَرْثٌ حِجْرٌ لَا يَطْعَمُهَا إِلَّا مَنْ نَشَاءُ بِزَعْمِهِمْ وَأَنْعَامٌ حُرِّمَتْ ظُهُورُهَا وَأَنْعَامٌ لَا يَذْكُرُونَ اسْمَ اللَّهِ عَلَيْهَا افْتِرَاءً عَلَيْهِ ۚ سَيَجْزِيهِمْ بِمَا كَانُوا يَفْتَرُونَ
Won tun wi pe: "Eewo ni awon eran-osin ati nnkan oko wonyi. Eni kan ko gbodo je e afi eni ti a ba fe, pelu oro won lai ni eri lowo." - Awon eran-osin kan tun n be ti won se eyin won ni eewo (fun gigun ati eru riru), awon eran kan tun n be ti won ki i fi oruko Allahu pa. (Won fi awon nnkan wonyi) da adapa iro mo Allahu ni. O si maa san won ni esan ohun ti won n da ni adapa iro
وَقَالُوا مَا فِي بُطُونِ هَٰذِهِ الْأَنْعَامِ خَالِصَةٌ لِذُكُورِنَا وَمُحَرَّمٌ عَلَىٰ أَزْوَاجِنَا ۖ وَإِنْ يَكُنْ مَيْتَةً فَهُمْ فِيهِ شُرَكَاءُ ۚ سَيَجْزِيهِمْ وَصْفَهُمْ ۚ إِنَّهُ حَكِيمٌ عَلِيمٌ
Won tun wi pe: "Ohun ti n be ninu ikun awon eran-osin wonyi je ti awon okunrin wa nikan soso, o si je eewo fun awon obinrin wa." Ti o ba si je oku omo-eran, akegbe si ni won ninu (ipin) re. (Allahu) yoo san won ni esan iro (enu) won. Dajudaju Oun ni Ologbon, Onimo
قَدْ خَسِرَ الَّذِينَ قَتَلُوا أَوْلَادَهُمْ سَفَهًا بِغَيْرِ عِلْمٍ وَحَرَّمُوا مَا رَزَقَهُمُ اللَّهُ افْتِرَاءً عَلَى اللَّهِ ۚ قَدْ ضَلُّوا وَمَا كَانُوا مُهْتَدِينَ
Awon t’o fi ago ati aimo pa awon omo won kuku ti sofo; won tun se ohun ti Allahu pa lese fun won ni eewo, ni ti dida adapa iro mo Allahu. Won kuku ti sina, won ko si je olumona
وَهُوَ الَّذِي أَنْشَأَ جَنَّاتٍ مَعْرُوشَاتٍ وَغَيْرَ مَعْرُوشَاتٍ وَالنَّخْلَ وَالزَّرْعَ مُخْتَلِفًا أُكُلُهُ وَالزَّيْتُونَ وَالرُّمَّانَ مُتَشَابِهًا وَغَيْرَ مُتَشَابِهٍ ۚ كُلُوا مِنْ ثَمَرِهِ إِذَا أَثْمَرَ وَآتُوا حَقَّهُ يَوْمَ حَصَادِهِ ۖ وَلَا تُسْرِفُوا ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O seda awon nnkan ogba oko eyi ti e n fowo ara yin gbin ati eyi t’o n lale hu ati dabinu ati irugbin ti (adun) jije re yato sira won, ati eso zaetun ati eso rummon t’o jora won ati eyi ti ko jora won. E je ninu eso re nigba ti o ba so, ki e si yo Zakah re ni ojo ikore re. Ki e si ma yapa. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon apa
وَمِنَ الْأَنْعَامِ حَمُولَةً وَفَرْشًا ۚ كُلُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ وَلَا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ ۚ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُبِينٌ
O si n be ninu awon eran-osin, eyi t’o le ru eru ati eyi ti ko le ru eru. E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin. Ki e si ma se tele awon oju-ese Esu; dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin

Choose other languages: