Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #144 Translated in Yoruba

قَدْ خَسِرَ الَّذِينَ قَتَلُوا أَوْلَادَهُمْ سَفَهًا بِغَيْرِ عِلْمٍ وَحَرَّمُوا مَا رَزَقَهُمُ اللَّهُ افْتِرَاءً عَلَى اللَّهِ ۚ قَدْ ضَلُّوا وَمَا كَانُوا مُهْتَدِينَ
Awon t’o fi ago ati aimo pa awon omo won kuku ti sofo; won tun se ohun ti Allahu pa lese fun won ni eewo, ni ti dida adapa iro mo Allahu. Won kuku ti sina, won ko si je olumona
وَهُوَ الَّذِي أَنْشَأَ جَنَّاتٍ مَعْرُوشَاتٍ وَغَيْرَ مَعْرُوشَاتٍ وَالنَّخْلَ وَالزَّرْعَ مُخْتَلِفًا أُكُلُهُ وَالزَّيْتُونَ وَالرُّمَّانَ مُتَشَابِهًا وَغَيْرَ مُتَشَابِهٍ ۚ كُلُوا مِنْ ثَمَرِهِ إِذَا أَثْمَرَ وَآتُوا حَقَّهُ يَوْمَ حَصَادِهِ ۖ وَلَا تُسْرِفُوا ۚ إِنَّهُ لَا يُحِبُّ الْمُسْرِفِينَ
(Allahu) Oun ni Eni ti O seda awon nnkan ogba oko eyi ti e n fowo ara yin gbin ati eyi t’o n lale hu ati dabinu ati irugbin ti (adun) jije re yato sira won, ati eso zaetun ati eso rummon t’o jora won ati eyi ti ko jora won. E je ninu eso re nigba ti o ba so, ki e si yo Zakah re ni ojo ikore re. Ki e si ma yapa. Dajudaju (Allahu) ko nifee awon apa
وَمِنَ الْأَنْعَامِ حَمُولَةً وَفَرْشًا ۚ كُلُوا مِمَّا رَزَقَكُمُ اللَّهُ وَلَا تَتَّبِعُوا خُطُوَاتِ الشَّيْطَانِ ۚ إِنَّهُ لَكُمْ عَدُوٌّ مُبِينٌ
O si n be ninu awon eran-osin, eyi t’o le ru eru ati eyi ti ko le ru eru. E je ninu ohun ti Allahu pa lese fun yin. Ki e si ma se tele awon oju-ese Esu; dajudaju oun ni ota ponnbele fun yin
ثَمَانِيَةَ أَزْوَاجٍ ۖ مِنَ الضَّأْنِ اثْنَيْنِ وَمِنَ الْمَعْزِ اثْنَيْنِ ۗ قُلْ آلذَّكَرَيْنِ حَرَّمَ أَمِ الْأُنْثَيَيْنِ أَمَّا اشْتَمَلَتْ عَلَيْهِ أَرْحَامُ الْأُنْثَيَيْنِ ۖ نَبِّئُونِي بِعِلْمٍ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
(Allahu da eran) mejo ni tako-tabo; meji ninu agutan (tako-tabo), meji ninu ewure (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. E fun mi ni iro pelu imo ti e ba je olododo
وَمِنَ الْإِبِلِ اثْنَيْنِ وَمِنَ الْبَقَرِ اثْنَيْنِ ۗ قُلْ آلذَّكَرَيْنِ حَرَّمَ أَمِ الْأُنْثَيَيْنِ أَمَّا اشْتَمَلَتْ عَلَيْهِ أَرْحَامُ الْأُنْثَيَيْنِ ۖ أَمْ كُنْتُمْ شُهَدَاءَ إِذْ وَصَّاكُمُ اللَّهُ بِهَٰذَا ۚ فَمَنْ أَظْلَمُ مِمَّنِ افْتَرَىٰ عَلَى اللَّهِ كَذِبًا لِيُضِلَّ النَّاسَ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۗ إِنَّ اللَّهَ لَا يَهْدِي الْقَوْمَ الظَّالِمِينَ
Meji ninu rakunmi (tako-tabo) ati meji ninu maalu (tako-tabo). So pe: "Se awon ako mejeeji ni Allahu se ni eewo ni tabi abo mejeeji, tabi ohun ti n be ninu apo-ibimo awon abo eran mejeeji. Tabi se eyin wa nibe nigba ti Allahu pa yin lase eyi ni?" Nitori naa, ta ni o se abosi t’o tun tayo eni t’o da adapa iro mo Allahu lati le si awon eniyan lona pelu ainimo. Dajudaju Allahu ko nii fi ona mo ijo alabosi

Choose other languages: