Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #127 Translated in Yoruba

وَكَذَٰلِكَ جَعَلْنَا فِي كُلِّ قَرْيَةٍ أَكَابِرَ مُجْرِمِيهَا لِيَمْكُرُوا فِيهَا ۖ وَمَا يَمْكُرُونَ إِلَّا بِأَنْفُسِهِمْ وَمَا يَشْعُرُونَ
Bayen ni A se so awon agba kan di odaran ilu ninu ilu kookan, nitori ki won le maa dete nibe. Won ko si dete si enikeni bi ko se si ara won, won ko si fura
وَإِذَا جَاءَتْهُمْ آيَةٌ قَالُوا لَنْ نُؤْمِنَ حَتَّىٰ نُؤْتَىٰ مِثْلَ مَا أُوتِيَ رُسُلُ اللَّهِ ۘ اللَّهُ أَعْلَمُ حَيْثُ يَجْعَلُ رِسَالَتَهُ ۗ سَيُصِيبُ الَّذِينَ أَجْرَمُوا صَغَارٌ عِنْدَ اللَّهِ وَعَذَابٌ شَدِيدٌ بِمَا كَانُوا يَمْكُرُونَ
Nigba ti ayah kan ba si de ba won, won a wi pe: “Awa ko nii gba a gbo titi di igba ti won ba to fun awa naa ni iru ohun ti won fun awon Ojise Allahu.” Allahu nimo julo nipa ibi ti O n fi ise-riran Re si. Laipe iyepere ati iya lile lati odo Allahu yoo de ba awon t’o dese nitori ohun ti won n da lete
فَمَنْ يُرِدِ اللَّهُ أَنْ يَهْدِيَهُ يَشْرَحْ صَدْرَهُ لِلْإِسْلَامِ ۖ وَمَنْ يُرِدْ أَنْ يُضِلَّهُ يَجْعَلْ صَدْرَهُ ضَيِّقًا حَرَجًا كَأَنَّمَا يَصَّعَّدُ فِي السَّمَاءِ ۚ كَذَٰلِكَ يَجْعَلُ اللَّهُ الرِّجْسَ عَلَى الَّذِينَ لَا يُؤْمِنُونَ
Enikeni ti Allahu ba fe fona mo, O maa si igba-aya re paya fun ’Islam. Enikeni ti O ba si fe si lona, O maa fun igba-aya re pa gadigadi bi eni pe o n gunke lo sinu sanmo. Bayen ni Allahu se de wahala asan si awon ti ko gbagbo
وَهَٰذَا صِرَاطُ رَبِّكَ مُسْتَقِيمًا ۗ قَدْ فَصَّلْنَا الْآيَاتِ لِقَوْمٍ يَذَّكَّرُونَ
Eyi ni oju ona Oluwa re (t’o je) ona taara. A kuku ti salaye awon ayah fun ijo t’o n lo iranti
لَهُمْ دَارُ السَّلَامِ عِنْدَ رَبِّهِمْ ۖ وَهُوَ وَلِيُّهُمْ بِمَا كَانُوا يَعْمَلُونَ
Ile alaafia n be fun won ni odo Oluwa won. Oun si ni Alatileyin won nipa ohun ti won n se nise

Choose other languages: