Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Anaam Ayahs #103 Translated in Yoruba

وَهُوَ الَّذِي أَنْزَلَ مِنَ السَّمَاءِ مَاءً فَأَخْرَجْنَا بِهِ نَبَاتَ كُلِّ شَيْءٍ فَأَخْرَجْنَا مِنْهُ خَضِرًا نُخْرِجُ مِنْهُ حَبًّا مُتَرَاكِبًا وَمِنَ النَّخْلِ مِنْ طَلْعِهَا قِنْوَانٌ دَانِيَةٌ وَجَنَّاتٍ مِنْ أَعْنَابٍ وَالزَّيْتُونَ وَالرُّمَّانَ مُشْتَبِهًا وَغَيْرَ مُتَشَابِهٍ ۗ انْظُرُوا إِلَىٰ ثَمَرِهِ إِذَا أَثْمَرَ وَيَنْعِهِ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكُمْ لَآيَاتٍ لِقَوْمٍ يُؤْمِنُونَ
Oun ni Eni t’O n so omi kale lati sanmo. A fi mu gbogbo nnkan ogbin jade. A tun mu eweko t’o n dan logbologbo jade lati inu re. A tun n mu siri eso jade ninu re. (A si n mu jade) lati ara igi dabinu, lati ara eso akoyo re, eso t’o sujo mora won t’o ro dede wale. (A n se) awon ogba oko eso ajara, eso zaetun ati eso rummon (ni awon eso t’o) jora ati (awon eyi ti) ko jora. E wo eso re nigba ti o ba so ati (nigba ti o ba) pon. Dajudaju awon ami wa ninu iyen fun ijo onigbagbo ododo
وَجَعَلُوا لِلَّهِ شُرَكَاءَ الْجِنَّ وَخَلَقَهُمْ ۖ وَخَرَقُوا لَهُ بَنِينَ وَبَنَاتٍ بِغَيْرِ عِلْمٍ ۚ سُبْحَانَهُ وَتَعَالَىٰ عَمَّا يَصِفُونَ
Won si fi awon alujannu se akegbe fun Allahu. Oun si l’O sedaa won! Won tun paro mo On (pe) O bi omokunrin ati omobinrin, lai nimo kan (nipa Re). Mimo ni fun Un. O si ga tayo ohun ti won n fi royin (Re)
بَدِيعُ السَّمَاوَاتِ وَالْأَرْضِ ۖ أَنَّىٰ يَكُونُ لَهُ وَلَدٌ وَلَمْ تَكُنْ لَهُ صَاحِبَةٌ ۖ وَخَلَقَ كُلَّ شَيْءٍ ۖ وَهُوَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمٌ
Olupileda awon sanmo ati ile ni. Bawo ni O se ni omo nigba ti ko ni aya. O da gbogbo nnkan. Oun si ni Onimo nipa gbogbo nnkan
ذَٰلِكُمُ اللَّهُ رَبُّكُمْ ۖ لَا إِلَٰهَ إِلَّا هُوَ ۖ خَالِقُ كُلِّ شَيْءٍ فَاعْبُدُوهُ ۚ وَهُوَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ وَكِيلٌ
Iyen ni Allahu, Oluwa yin; ko si olohun kan ti ijosin to si afi Oun, Eledaa gbogbo nnkan. Nitori naa, e josin fun Un. Oun si ni Oluso lori gbogbo nnkan
لَا تُدْرِكُهُ الْأَبْصَارُ وَهُوَ يُدْرِكُ الْأَبْصَارَ ۖ وَهُوَ اللَّطِيفُ الْخَبِيرُ
Awon oju (eda) ko le ka Allahu. Oun si ka awon oju. Oun si ni Alaaanu, Alamotan

Choose other languages: