Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #57 Translated in Yoruba

يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا لَا تَدْخُلُوا بُيُوتَ النَّبِيِّ إِلَّا أَنْ يُؤْذَنَ لَكُمْ إِلَىٰ طَعَامٍ غَيْرَ نَاظِرِينَ إِنَاهُ وَلَٰكِنْ إِذَا دُعِيتُمْ فَادْخُلُوا فَإِذَا طَعِمْتُمْ فَانْتَشِرُوا وَلَا مُسْتَأْنِسِينَ لِحَدِيثٍ ۚ إِنَّ ذَٰلِكُمْ كَانَ يُؤْذِي النَّبِيَّ فَيَسْتَحْيِي مِنْكُمْ ۖ وَاللَّهُ لَا يَسْتَحْيِي مِنَ الْحَقِّ ۚ وَإِذَا سَأَلْتُمُوهُنَّ مَتَاعًا فَاسْأَلُوهُنَّ مِنْ وَرَاءِ حِجَابٍ ۚ ذَٰلِكُمْ أَطْهَرُ لِقُلُوبِكُمْ وَقُلُوبِهِنَّ ۚ وَمَا كَانَ لَكُمْ أَنْ تُؤْذُوا رَسُولَ اللَّهِ وَلَا أَنْ تَنْكِحُوا أَزْوَاجَهُ مِنْ بَعْدِهِ أَبَدًا ۚ إِنَّ ذَٰلِكُمْ كَانَ عِنْدَ اللَّهِ عَظِيمًا
Eyin ti e gbagbo ni ododo, e ma se wo awon inu ile Anabi afi ti won ba yonda fun yin lati wole jeun lai nii je eni ti yoo maa reti ki ounje jinna, sugbon ti won ba pe yin (fun ounje) e wo inu ile nigba naa. Nigba ti e ba si jeun tan, e tuka, e ma se jokoo kale tira yin fun oro kan mo (ninu ile re). Dajudaju iyen n ko inira ba Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). O si n tiju yin. Allahu ko si nii tiju nibi ododo. Nigba ti e ba si fe beere nnkan ni odo awon iyawo re, e beere re ni odo won ni eyin gaga. Iyen je afomo julo fun okan yin ati okan won. Ko to fun yin lati ko inira ba Ojise Allahu. (Ko si to fun yin) lati fe awon iyawo re leyin (iku) re laelae. Dajudaju iyen je nnkan nla ni odo Allahu
إِنْ تُبْدُوا شَيْئًا أَوْ تُخْفُوهُ فَإِنَّ اللَّهَ كَانَ بِكُلِّ شَيْءٍ عَلِيمًا
Ti e ba safi han kini kan tabi e fi pamo, dajudaju Allahu n je Onimo nipa gbogbo nnkan
لَا جُنَاحَ عَلَيْهِنَّ فِي آبَائِهِنَّ وَلَا أَبْنَائِهِنَّ وَلَا إِخْوَانِهِنَّ وَلَا أَبْنَاءِ إِخْوَانِهِنَّ وَلَا أَبْنَاءِ أَخَوَاتِهِنَّ وَلَا نِسَائِهِنَّ وَلَا مَا مَلَكَتْ أَيْمَانُهُنَّ ۗ وَاتَّقِينَ اللَّهَ ۚ إِنَّ اللَّهَ كَانَ عَلَىٰ كُلِّ شَيْءٍ شَهِيدًا
Ko si ese fun awon iyawo Anabi nipa awon baba won ati awon omokunrin won ati awon arakunrin won ati awon omokunrin arakunrin won ati awon omokunrin arabinrin won ati awon obinrin (egbe) won ati awon erukunrin won (lati wole ti won.) E beru Allahu. Dajudaju Allahu n je Arinu-rode gbogbo nnkan
إِنَّ اللَّهَ وَمَلَائِكَتَهُ يُصَلُّونَ عَلَى النَّبِيِّ ۚ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا صَلُّوا عَلَيْهِ وَسَلِّمُوا تَسْلِيمًا
Dajudaju Allahu ati awon molaika Re n ke Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). Eyin ti e gbagbo ni ododo, e toro ike fun un, ki e si ki i ni kiki alaafia. awon Sohabah naa (r.ahm) maa n se bee. Eyin naa e wo bi awon aafa sunnah se n se asolatu fun Anabi ninu awon oro isaaju ninu awon tira won. Ko si aburu ninu eyi rara. Sugbon musulumi yoo se agbekale ihun asolatu daran ti o ba fi le ko sinu okan ninu awon nnkan mefa kan. Ikini: Lilo awon oro ti o lodi si ofin ati adisokan ’Islam ninu awon gbolohun asolatu naa. Ikeji: Siso gbolohun asolatu yen gan-angan di ilana ti won yoo maa pepe si ti irufe gbolohun naa yoo fi wa da bi eni pe hadith kan l’o gba a wa
إِنَّ الَّذِينَ يُؤْذُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ لَعَنَهُمُ اللَّهُ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَأَعَدَّ لَهُمْ عَذَابًا مُهِينًا
Dajudaju awon t’o n fi inira kan Allahu ati Ojise Re, Allahu ti sebi le won nile aye ati ni orun. O si ti pese iya t’o n yepere eda sile de won

Choose other languages: