Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #60 Translated in Yoruba

إِنَّ اللَّهَ وَمَلَائِكَتَهُ يُصَلُّونَ عَلَى النَّبِيِّ ۚ يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا صَلُّوا عَلَيْهِ وَسَلِّمُوا تَسْلِيمًا
Dajudaju Allahu ati awon molaika Re n ke Anabi (sollalahu alayhi wa sallam). Eyin ti e gbagbo ni ododo, e toro ike fun un, ki e si ki i ni kiki alaafia. awon Sohabah naa (r.ahm) maa n se bee. Eyin naa e wo bi awon aafa sunnah se n se asolatu fun Anabi ninu awon oro isaaju ninu awon tira won. Ko si aburu ninu eyi rara. Sugbon musulumi yoo se agbekale ihun asolatu daran ti o ba fi le ko sinu okan ninu awon nnkan mefa kan. Ikini: Lilo awon oro ti o lodi si ofin ati adisokan ’Islam ninu awon gbolohun asolatu naa. Ikeji: Siso gbolohun asolatu yen gan-angan di ilana ti won yoo maa pepe si ti irufe gbolohun naa yoo fi wa da bi eni pe hadith kan l’o gba a wa
إِنَّ الَّذِينَ يُؤْذُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ لَعَنَهُمُ اللَّهُ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَأَعَدَّ لَهُمْ عَذَابًا مُهِينًا
Dajudaju awon t’o n fi inira kan Allahu ati Ojise Re, Allahu ti sebi le won nile aye ati ni orun. O si ti pese iya t’o n yepere eda sile de won
وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ بِغَيْرِ مَا اكْتَسَبُوا فَقَدِ احْتَمَلُوا بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُبِينًا
Awon t’o n fi inira kan awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin nipa nnkan ti won ko se, dajudaju won ti ru eru (oran) iparomoni ati ese ponnbele
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ قُلْ لِأَزْوَاجِكَ وَبَنَاتِكَ وَنِسَاءِ الْمُؤْمِنِينَ يُدْنِينَ عَلَيْهِنَّ مِنْ جَلَابِيبِهِنَّ ۚ ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَنْ يُعْرَفْنَ فَلَا يُؤْذَيْنَ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
Iwo Anabi so fun awon iyawo re, awon omobinrin re ati awon obinrin onigbagbo ododo pe ki won maa gbe awon aso jilbab won wo si ara won bamubamu. Iyen sunmo julo lati fi mo won (ni oluberu Allahu). Nipa bee, won ko nii fi inira kan won. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
لَئِنْ لَمْ يَنْتَهِ الْمُنَافِقُونَ وَالَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ وَالْمُرْجِفُونَ فِي الْمَدِينَةِ لَنُغْرِيَنَّكَ بِهِمْ ثُمَّ لَا يُجَاوِرُونَكَ فِيهَا إِلَّا قَلِيلًا
Ti awon sobe-selu musulumi, ati awon ti aisan n be ninu okan won ati awon tuletule ninu ilu Modinah ko ba jawo (nibi aburu), dajudaju A maa de o si won, (o si maa bori won). Leyin naa, won ko si nii ba o gbe adugbo po mo afi fun igba die

Choose other languages: