Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahzab Ayahs #61 Translated in Yoruba

إِنَّ الَّذِينَ يُؤْذُونَ اللَّهَ وَرَسُولَهُ لَعَنَهُمُ اللَّهُ فِي الدُّنْيَا وَالْآخِرَةِ وَأَعَدَّ لَهُمْ عَذَابًا مُهِينًا
Dajudaju awon t’o n fi inira kan Allahu ati Ojise Re, Allahu ti sebi le won nile aye ati ni orun. O si ti pese iya t’o n yepere eda sile de won
وَالَّذِينَ يُؤْذُونَ الْمُؤْمِنِينَ وَالْمُؤْمِنَاتِ بِغَيْرِ مَا اكْتَسَبُوا فَقَدِ احْتَمَلُوا بُهْتَانًا وَإِثْمًا مُبِينًا
Awon t’o n fi inira kan awon onigbagbo ododo lokunrin ati onigbagbo ododo lobinrin nipa nnkan ti won ko se, dajudaju won ti ru eru (oran) iparomoni ati ese ponnbele
يَا أَيُّهَا النَّبِيُّ قُلْ لِأَزْوَاجِكَ وَبَنَاتِكَ وَنِسَاءِ الْمُؤْمِنِينَ يُدْنِينَ عَلَيْهِنَّ مِنْ جَلَابِيبِهِنَّ ۚ ذَٰلِكَ أَدْنَىٰ أَنْ يُعْرَفْنَ فَلَا يُؤْذَيْنَ ۗ وَكَانَ اللَّهُ غَفُورًا رَحِيمًا
Iwo Anabi so fun awon iyawo re, awon omobinrin re ati awon obinrin onigbagbo ododo pe ki won maa gbe awon aso jilbab won wo si ara won bamubamu. Iyen sunmo julo lati fi mo won (ni oluberu Allahu). Nipa bee, won ko nii fi inira kan won. Allahu si n je Alaforijin, Asake-orun
لَئِنْ لَمْ يَنْتَهِ الْمُنَافِقُونَ وَالَّذِينَ فِي قُلُوبِهِمْ مَرَضٌ وَالْمُرْجِفُونَ فِي الْمَدِينَةِ لَنُغْرِيَنَّكَ بِهِمْ ثُمَّ لَا يُجَاوِرُونَكَ فِيهَا إِلَّا قَلِيلًا
Ti awon sobe-selu musulumi, ati awon ti aisan n be ninu okan won ati awon tuletule ninu ilu Modinah ko ba jawo (nibi aburu), dajudaju A maa de o si won, (o si maa bori won). Leyin naa, won ko si nii ba o gbe adugbo po mo afi fun igba die
مَلْعُونِينَ ۖ أَيْنَمَا ثُقِفُوا أُخِذُوا وَقُتِّلُوا تَقْتِيلًا
Won di eni-isebile nibikibi ti owo ba ti ba won; won maa mu won, won si maa pa won taara

Choose other languages: