Quran Apps in many lanuages:

Surah Al-Ahqaf Ayahs #8 Translated in Yoruba

قُلْ أَرَأَيْتُمْ مَا تَدْعُونَ مِنْ دُونِ اللَّهِ أَرُونِي مَاذَا خَلَقُوا مِنَ الْأَرْضِ أَمْ لَهُمْ شِرْكٌ فِي السَّمَاوَاتِ ۖ ائْتُونِي بِكِتَابٍ مِنْ قَبْلِ هَٰذَا أَوْ أَثَارَةٍ مِنْ عِلْمٍ إِنْ كُنْتُمْ صَادِقِينَ
So pe: "E so fun mi nipa nnkan ti e n pe leyin Allahu; e fi won han mi na, ki ni won seda ninu (ohun t’o wa lori) ile. Tabi won ni ipin kan (pelu Allahu) ninu (iseda) awon sanmo? E mu Tira kan wa fun mi t’o siwaju (al-Ƙur’an) yii tabi oripa kan ninu imo ti e ba je olododo
وَمَنْ أَضَلُّ مِمَّنْ يَدْعُو مِنْ دُونِ اللَّهِ مَنْ لَا يَسْتَجِيبُ لَهُ إِلَىٰ يَوْمِ الْقِيَامَةِ وَهُمْ عَنْ دُعَائِهِمْ غَافِلُونَ
Ta l’o si sina ju eni ti o n pe leyin Allahu, eni ti ko le je ipe re titi di Ojo Ajinde! Ati pe won ko ni oye si pipe ti won n pe won
وَإِذَا حُشِرَ النَّاسُ كَانُوا لَهُمْ أَعْدَاءً وَكَانُوا بِعِبَادَتِهِمْ كَافِرِينَ
Nigba ti A ba si ko awon eniyan jo (fun Ajinde), awon orisa yoo di ota fun awon aborisa. Won si maa tako ijosin ti won se fun won
وَإِذَا تُتْلَىٰ عَلَيْهِمْ آيَاتُنَا بَيِّنَاتٍ قَالَ الَّذِينَ كَفَرُوا لِلْحَقِّ لَمَّا جَاءَهُمْ هَٰذَا سِحْرٌ مُبِينٌ
Nigba ti won ba n ke awon ayah Wa t’o yanju fun won, awon t’o sai gbagbo yo si maa so isokuso si ododo nigba ti o de ba won pe: "Eyi ni idan ponnbele
أَمْ يَقُولُونَ افْتَرَاهُ ۖ قُلْ إِنِ افْتَرَيْتُهُ فَلَا تَمْلِكُونَ لِي مِنَ اللَّهِ شَيْئًا ۖ هُوَ أَعْلَمُ بِمَا تُفِيضُونَ فِيهِ ۖ كَفَىٰ بِهِ شَهِيدًا بَيْنِي وَبَيْنَكُمْ ۖ وَهُوَ الْغَفُورُ الرَّحِيمُ
Tabi won n wi pe: "O da (al-Ƙur’an) hun funra re ni." So pe: "Ti mo ba hun un funra mi, e o ni ikapa kini kan fun mi ni odo Allahu (nibi iya Re). Oun ni Onimo-julo nipa isokuso ti e n so nipa re. O (si) to ni Elerii laaarin emi ati eyin. Oun ni Alaforijin, Asake-orun

Choose other languages: