Surah Aal-E-Imran Ayahs #53 Translated in Yoruba
وَرَسُولًا إِلَىٰ بَنِي إِسْرَائِيلَ أَنِّي قَدْ جِئْتُكُمْ بِآيَةٍ مِنْ رَبِّكُمْ ۖ أَنِّي أَخْلُقُ لَكُمْ مِنَ الطِّينِ كَهَيْئَةِ الطَّيْرِ فَأَنْفُخُ فِيهِ فَيَكُونُ طَيْرًا بِإِذْنِ اللَّهِ ۖ وَأُبْرِئُ الْأَكْمَهَ وَالْأَبْرَصَ وَأُحْيِي الْمَوْتَىٰ بِإِذْنِ اللَّهِ ۖ وَأُنَبِّئُكُمْ بِمَا تَأْكُلُونَ وَمَا تَدَّخِرُونَ فِي بُيُوتِكُمْ ۚ إِنَّ فِي ذَٰلِكَ لَآيَةً لَكُمْ إِنْ كُنْتُمْ مُؤْمِنِينَ
(O si je) Ojise (ti A ran nise) si awon omo ’Isro’il. (O si maa so fun won pe) "Dajudaju emi ti mu ami kan wa fun yin lati odo Oluwa yin. Dajudaju emi yoo mo nnkan fun yin lati inu amo bi irisi eye. Emi yoo fe ategun sinu re. O si maa di eye pelu iyonda Allahu. Emi yoo se iwosan fun afoju ati adete, mo si maa so oku di alaaye pelu iyonda Allahu. Emi yoo maa fun yin ni iro ohun ti e n je ati ohun ti e n fi pamo sinu ile yin. Dajudaju ami kan wa ninu iyen fun yin, ti e ba je onigbagbo ododo
وَمُصَدِّقًا لِمَا بَيْنَ يَدَيَّ مِنَ التَّوْرَاةِ وَلِأُحِلَّ لَكُمْ بَعْضَ الَّذِي حُرِّمَ عَلَيْكُمْ ۚ وَجِئْتُكُمْ بِآيَةٍ مِنْ رَبِّكُمْ فَاتَّقُوا اللَّهَ وَأَطِيعُونِ
Mo si n fi ohun t’o je ododo rinle nipa eyi t’o siwaju mi ninu Taorah nitori ki emi le se ni eto fun yin apa kan eyi ti won se ni eewo fun yin. Mo ti mu ami kan wa fun yin lati odo Oluwa yin. Nitori naa, e beru Allahu, ki e si tele mi
إِنَّ اللَّهَ رَبِّي وَرَبُّكُمْ فَاعْبُدُوهُ ۗ هَٰذَا صِرَاطٌ مُسْتَقِيمٌ
Dajudaju Allahu ni Oluwa mi ati Oluwa yin. Nitori naa, e josin fun Un. Eyi ni ona taara
فَلَمَّا أَحَسَّ عِيسَىٰ مِنْهُمُ الْكُفْرَ قَالَ مَنْ أَنْصَارِي إِلَى اللَّهِ ۖ قَالَ الْحَوَارِيُّونَ نَحْنُ أَنْصَارُ اللَّهِ آمَنَّا بِاللَّهِ وَاشْهَدْ بِأَنَّا مُسْلِمُونَ
Nigba ti (Anabi) ‘Isa fura si aigbagbo lodo won (pe won fe pa oun), o so pe: “Ta ni oluranlowo mi si odo Allahu?” Awon omoleyin (re) so pe: "Awa ni oluranlowo fun (esin) Allahu. A gba Allahu gbo. Ki o si jerii pe dajudaju musulumi ni wa
رَبَّنَا آمَنَّا بِمَا أَنْزَلْتَ وَاتَّبَعْنَا الرَّسُولَ فَاكْتُبْنَا مَعَ الشَّاهِدِينَ
Oluwa wa, a gbagbo ninu ohun ti O sokale. A si tele Ojise. Nitori naa, ko wa mo awon olujerii
Choose other languages:

Albanian

Amharic

Azerbaijani

Bengali

Bosnian

Bulgarian

Burmese

Chinese

Danish

Dutch

English

Farsi

Filipino

French

Fulah

German

Gujarati

Hausa

Hindi

Indonesian

Italian

Japanese

Jawa

Kazakh

Khmer

Korean

Kurdish

Kyrgyz

Malay

Malayalam

Norwegian

Pashto

Persian

Polish

Portuguese

Punjabi

Russian

Sindhi

Sinhalese

Somali

Spanish

Swahili

Swedish

Tajik

Tamil

Tatar

Telugu

Thai

Turkish

Urdu

Uyghur

Uzbek

Vietnamese

Yoruba
